A o ti i yan Gbadegẹṣin sipo Alaafin o- Ọyọmesi

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi iroyin kan ṣe n ja ran-in ran-in kiri pe orukọ ẹni ti yoo jẹ Alaafin Ọyọ ti wa lọdọ ijọba ipinlẹ Ọyọ, ki wọn kan kede ẹ, ki wọn si gbe ọpa aṣẹ le e lọwọ lo ku, awọn Ọyọmesi, iyẹn igbimọ awọn afọbajẹ ilu Ọyọ ti ta ko iroyin naa, wọn ni irọ gbuu lasan ni.

Ọkan ninu awọn to n dupo ọba Ọyọ lọwọlọwọ, Ọmọọba Lukman Gbadegẹṣin, la gbọ pe awọn Afọbajẹ n gbe igbesẹ lati fi i jẹ Alaafin bayii, wọn ni wọn ti fi orukọ ọkunrin naa ṣọwọ si ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ to n ri ṣi ọrọ oye jijẹ.

Ṣugbọn Baṣọrun Ọyọ, Agba-Oye Yusuf Ọlayinka, Ayọọla, to tun jẹ olori igbimọ awọn afọbajẹ Ọyọ ti ta ko iroyin yii, o ni awọn afọbajẹ ilu naa ko ti i fa ẹnikẹni kalẹ ninu awọn to n dupo ọba naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “A ṣẹṣẹ pari ifọrọwanilẹnuwo fawọn ọmọ oye ni, a o si ti i fi orukọ kankan ranṣẹ si ijọba n’Ibadan. Ibi ti wọn waa ti gbọ iroyin yẹn ni ko ye mi”.

Ṣaaju, iyẹn ninu ipade oniroyin to ṣe lopin ọsẹ to kọja, l’Ọmọọba Hammed Isiaka Adelabu, ti bu ẹnu atẹ lu iroyin yii, o ni oun jẹrii awọn Ọyọmesi, wọn ko le deede yan eeyan sipo Alaafin bẹẹ lai jẹ pe wọn ti ṣe iwadii gbogbo to ba yẹ ki wọn ṣe.

Ninu ọrọ tiẹ, Agbaakin ilu Ọyọ, Oloye Asimiyu Jimoh, sọ pe “Emi o mọ nnkan kan nipa orukọ ti wọn sọ pe wọn fi ranṣẹ si ijọba o. Nnkan ti awọn ijọba funra wọn sọ ninu ipade ta a ṣe gbẹyin ni pe ẹnikẹni ta a ba maa mu gẹgẹ bii Alaafin, a gbọdọ kọ orukọ ẹni naa sinu lẹta, ki gbogbo awa afọbajẹ si mu lẹta yẹn wa sọdọ ijọba n’Ibadan ni.

“Wọn ni ijọba lo maa kede Alaafin tuntun, orukọ ẹni ta a ba si mu wa sọdọ ijọba nijọba maa kede. Nitori naa, ọrọ pe wọn ti dọgbọn mu orukọ ẹnikan lọ sọdọ ijọba ni kọrọ yẹn ko ṣẹlẹ rara”.

Leave a Reply