Monisọla Saka
Ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe idagbasoke ati itẹsiwaju to lọọrin ti de ba ilẹ Naijiria ju bo ṣe wa lọdun 2015, nigba tawọn ẹgbẹ alatako, iyẹn PDP, wa nipo lọ.
Minisita fọrọ aṣa ati eto iroyin, Alaaji Lai Muhammed, lo sọ eleyii di mimọ lọjọ Aje, Mọnde, Ogunjọ, oṣu Keji, ọdun yii, lori eto ti wọn maa n ṣe laaarọ kutukutu, eyi ti wọn n pe ni ‘Good Morning’, lori ikanni tẹlifiṣan NTA.
Lasiko to n sọrọ lori eto yii, o sọ pe gbogbo erongba awọn ọmọ Naijiria lori orilẹ-ede yii, ni ijọba Buhari ti muṣẹ, bẹẹ lo mu gbogbo ileri to ṣe ṣẹ ni gbedeke akoko to da. O ni iṣẹ ọwọ awọn ọbayejẹ, onisọkusọ, ti wọn ko laju, ti wọn ko si rikan ṣekan, ni gbogbo awọn ti wọn n gbe ọrọ ti ko daa, to le ba ijọba ati orilẹ-ede yii jẹ kiri.
Nigba to n sọrọ lori awọn ohun meremere ti ijọba ọhun ti gbe ṣe, minisita yii ni lọdun 2015, ko si ẹda to jẹ daṣa pe oun fẹẹ lọ si ẹkun apa Ila Oorun ariwa orilẹ-ede yii, bẹẹ lo jẹ pe ijọba ibilẹ ogun, ninu mẹtadinlọgbọn, to wa nibẹ lo wa labẹ iṣakoso awọn ikọ mujẹmujẹ Boko Haram lọdun naa lọhun-un.
O ni lọwọlọwọ bayii, ko si apa ibi kankan nilẹ Naijiria yii tawọn Boko Haram ti n jẹ gaba le wọn lori mọ.
O tẹsiwaju pe ni gbogbo ọdun 2015 ọhun naa, aṣaaju ni Naijiria jẹ laarin awọn orilẹ-ede ti wọn n ko irẹsi wọle lati ilẹ Thailand, ṣugbọn pẹlu eto ọgbin ti ijọba Buhari gbe kalẹ, ilẹ Naijiria ti le da duro bayii, o si le pese ounjẹ lọpọ yanturu fawọn eeyan ẹ.
O ni ọgọọrọ awọn agbẹ ni wọn ti janfaani eto ẹyawo ti wọn ro wọn lagbara, bẹẹ ni ibudo ti wọn ti n pese irẹsi nilẹ yii ti gbera lati ẹyọ meji pere si ọgọta. Lẹka eto ẹkọ bakan naa, awọn ọmọ ileewe alakọọbẹrẹ bii miliọnu mẹwaa ni wọn n jẹ ounjẹ ọfẹ lojumọ, nigba tawọn idile bii miliọnu meji naa jẹ anfaani owo-ọfẹ atawọn nnkan mi-in bẹẹ.
Lai fi kun un pe awọn ti ṣe oju ọna tuntun to gun bii iwọn kilomita ẹgbẹrun mẹtadinlogun, o ni ẹgbẹrun mẹjọ ọna to ti bajẹ lawọn ti wọn tunṣe.
O ni, “A ti pari opopona marosẹ Eko si Ibadan, bẹẹ naa la ti ṣe afara odo Niger keji, lohun to jẹ pe wọn ti sọ di apati lati bii ọgbọn ọdun sẹyin. Ni nnkan bii ọgbọn ọdun sẹyin yii naa, awọn ọmọ Naijiria ko mọ ohun to jẹ lati maa rinrin-ajo pẹlu ọkọ oju irin, afigba ti Buhari depo.
Pẹlu gbogbo ibajẹ ti wọn fi n kan ijọba wa, lonii, a ti ni reluwee to n na Eko si Ibadan, Abuja si Kaduna, ati Ajaokuta si Warri, ti gbogbo wọn si n ṣiṣẹ daadaa yatọ si ti ijọba ana tawọn araalu ko jẹ anfaani iru nnkan bayii labẹ iṣakoso wọn”.
Lai Muhammed ni, niwọnba ọjọ perete to ku, Buhari ko ni i tẹti lati tubọ mu ki orilẹ-ede yii goke agba si i, lai wo ti awọn ti wọn n sọ ohun toju wọn ko to.