Faith Adebọla, Eko
Ni itakora si ọrọ ti Gomina Babajide Sanwo-Olu sọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, pe oun ti paṣẹ pe ki wọn fi gbogbo awọn tọwọ agbofinro ba nibi iwọde ayajọ EndSARS to waye lagbegbe Lẹkki, nipinlẹ Eko, silẹ lalaafia, ki kaluku maa lọ ile rẹ layọ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni awọn eeyan mẹrinlelọgbọn lo ko sakolo awọn lọjọ naa, awọn si ti wọ wọn tuuru lọ sile-ẹjọ, lati ṣalaye ẹnu wọn niwaju adajọ.
Atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, CSP Adekunle Ajiṣebutu, fi ṣọwọ s’ALAROYE lori iṣẹlẹ ọhun fidi ẹ mulẹ pe lati nnkan bii aago mẹjọ owurọ si aago mẹwaa lawọn oluwọde naa ti bẹrẹ iwọde wọn, gbogbo nnkan si lọ wọọrọwọ, yatọ si idiwọ diẹ to wa fun lilọ bibọ ọkọ ni Too-geeti Lẹkki ọhun.
O ni ni nnkan bii aago mọkanla aabọ, lẹyin tawọn to waa ṣe iwọde ti pada sile wọn, lawọn janduku kan ko ara wọn de, wọn dara pọ mọ sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ to waye lasiko naa, wọn si fẹẹ maa ṣakọlu sawọn onimọto atawọn eeyan to n gba agbegbe yii kọja jẹẹjẹ wọn.
O lawọn janduku yii gun Ọgbẹni Ṣina Ẹdun, ẹṣọ alaabo Man ‘O’ War to n ṣiṣẹ pẹlu Lẹkki Concession Company, lọbẹ nikun. Ọpẹlọpẹ awọn alaaanu ti wọn sare gbe e lọ sileewosan kan, ibẹ lo wa titi di ba a ṣe n sọ yii, to n gba itọju.
Ajiṣebutu ni bawọn janduku ṣe fẹẹ dana ijangbọn yii lo mu kawọn ọlọpaa tete fi pampẹ ofin gbe wọn, ti wọn si yin afẹfẹ taju-taju si wọn lati tu wọn ka.
Afurasi ọdaran mẹrinlelọgbọn, ada meji, haama kan, ọbẹ aṣooro meji ati oogun abẹnugọngọ oriṣiiriṣii ni wọn gba lọwọ wọn, wọn si ti foju wọn bale-ẹjọ Majisireeti karun-un, eyi to wa l’Oṣodi, nipinlẹ Eko.
O ni meji ninu wọn jẹwọ pe awọn jẹbi, ile-ẹjọ si bu owo itanran ẹgbẹrun mẹwaa naira le ọkọọkan wọn. Ọgbọn lara wọn lo sọ pe awọn o jẹbi, ile-ẹjọ si gba beeli ọkọọkan wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna ogun naira (N20,000) ati oniduuro kọọkan ni iye owo naa.
Ile-ẹjọ naa da ẹni kan silẹ pe ko lẹjọ i jẹ, nigba ti wọn paṣẹ ki wọn lọọ fi Chukwu Chika, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ti wọn ka ada ati oogun abẹnugọngọ mọ lọwọ sahaamọ awọn ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii to lọọrin. Wọn lọkunrin naa ti jẹwọ ni kootu pe oun diidi wa lati huwa janduku lọjọ naa ni, wọn si ti sun igbẹjọ siwaju lori ọrọ rẹ.
Ṣaaju ni gomina ipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki wọn tu gbogbo awọn ti wọn mu nibi iwọde naa silẹ, Sanwo-Olu sọrọ yii lọjọ iṣẹlẹ ọhun, o ni ẹlẹyinju aanu ni ijọba ipinlẹ Eko, ati pe awọn nifẹẹ awọn ọdọ, awọn si mọyi bi wọn ṣe jẹ ki iwọde wọn lọ wọọrọwọ. O ni ijọba ti gbọ awọn ẹbẹ ati ibeere wọn, awọn o si ni i sinmi lati ri i pe awọn tẹ awọn ọdọ naa lọrun.
Ṣugbọn o sọ pe ki wọn ṣi maa ba iwadii lọ lori ẹni kan ti wọn ba nnkan ija oloro lara, ki wọn ma ti i fi oun silẹ ni tiẹ.
Bakan naa ni gomina tun sọ ninu ọrọ rẹ pe ko si awo kan ninu awo ẹwa lori abọ iwadii igbimọ tawọn gbekalẹ lati gbọ aroye awọn ti ọlọpaa ti fi ẹtọ wọn du tabi ti wọn fiya jẹ latẹyinwa, o ni gbogbo aba ati amọran to wa ninu abọ iwadii naa lawọn yoo ṣiṣẹ le lori bo ṣe yẹ.