Adewale Adeoye
Awọn agba bọ, wọn ni bo ba pẹ ta a ti n da obi, ọjọ kan lo maa yan, bẹẹ gan-an lo ri pẹlu ọrọ to jade lẹnu Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, pe gbogbo ilakaka lori eto ọrọ aje orileede yii ti de ebute ayọ. O ni laipẹ yii lawọn ọmọ Naijiria yoo bẹrẹ si i jẹgbadun ailopin.
Nibi eto ibura fun gomina tuntun nipinlẹ Edo, Ọgbẹni Monday Okpebholo, ni Aarẹ Tinubu ti sọrọ ọhun di mimọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima, to gbẹnu Aarẹ Tinubu sọrọ nibi eto pataki ọhun sọ pe pẹlu bawọn eeyan ipinlẹ Edo ṣe ti yan ẹni bii ọkan wọn sipo gomina ipinlẹ naa, o daju pe gbogbo nnkan yoo maa lọọ deede laarin ilu naa bayii.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘‘Aarẹ Tinubu ni ki n ki yin ku oriire fun bi ẹ ti ṣe yan ẹni bii ọkan yin sipo gomina ipinlẹ Edo. Ko si ani-ani nibẹ, igbesẹ gidi lẹ gbe yii, ọjọ iwaju ipinlẹ yii si daa gidi ni. Fun ti orileede Naijiria wa, akoko ilakaka nipa eto ọrọ-aje orileede yii ti de ebute ayọ, a ti la oke iṣoro to ga ju lọ kọja, ka maa jẹ igbadun lọ lo ku fun wa bayii.
Bakan naa ni Aarẹ Tinubu rọ gbogbo awọn oloṣelu ipinlẹ naa pe ki wọn fọwọ-sowọ-pọ pẹlu gomina ipinlẹ naa, ki erongba gidi rẹ le wa si imuṣẹ laipẹ yii.
O ni, ‘‘Asiko oṣelu ẹtanu ti kọja, akoko tẹ ẹ gbọdọ wa ni iṣọkan ati irẹpọ ree, ẹ ma ṣe faaye gba ija tabi rogbodiyan laarin yin. Ẹ ma ṣe gbiyanju lati da rogbodiyan silẹ laarin ilu, ẹ fọwọ-sowọ-pọ pẹlu gomina tuntun yii ni. Bẹẹ ni kawọn olori ti wọn dibo yan naa ṣiṣẹ takuntakun lati ṣe ohun taraalu n fẹ fun wọn’’.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu yii, ni gomina tuntun gba ọpa aṣẹ nipinlẹ Edo, lẹyin ọdun mẹjọ ti Godwin Obaseki ti wa nibẹ.