A ti mọ awọn ọbayejẹ to wa nidii iwọde tawọn araalu fẹẹ ṣe-Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ

Adewale adeoye

Birọ ni, bi ootọ ni, ko sẹnikan to mọ, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ (DSS) orileede yii lawọn ti mọ awọn ọbayejẹ ẹda ti wọn n ṣe agbatẹru ipolongo iwọde ita gbangba ti wọn fẹẹ ṣe laipẹ yii.

Alukoro ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lorileede yii, Ọgbẹni Peter Afunanya, lo sọrọ ọhun di mimọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje, ọdun yii, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ l’Abuja. O ni awọn ti ṣewadii nipa awọn ọbayejẹ ẹda naa, tawọn si ti da wọn mọ bayii.

Ṣa o, alukoro ọhun ko sọ ni pato iru igbesẹ tabi ohun ti wọn maa ṣe fawọn onitọhun, bẹẹ ni ko sọ boya wọn ti fọwọ ofin mu ẹnikẹni f’ohun ti wọn ni wọn ṣe naa.

Ki i ṣe tuntun mọ pe araalu atawọn ọdọ orileede yii lawọn maa ṣewọde ita gbangba lati ta ko iṣejọba Aarẹ Tinubu lori bi ilu ṣe le koko bayii.

Ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni wọn lawọn maa bẹrẹ iwọde naa. Bi nnkan ko ṣe fara ro laarin ilu wa lara ohun to n bi wọn ninu.

 

Leave a Reply