A ti tu Naira Marley ati Sam Larry silẹ lahaamọ o – Ọlọpaa 

Faith Adebọla

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tu awọn gbajumọ ọrẹ meji nni, Naira Marley ati Sam Larry, ti wọn ti wa lahaamọ wọn lori ẹsun lilọwọ ninu iku ojiji to pa irawọ onkọrin taka-sufee nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan mọ si Mohbad.

Aṣaalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ta a wa yii ni Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, SP Benjamin Hundeyin, sọ ọ di mimọ pe awọn ti yọnda AbdulAzeez Adeṣina Faṣọla, gbajugbaja onkọrin tawọn eeyan tun mọ si Naira Marley, ati ọrẹ rẹ kan toun maa n gbe awọn oṣere jade, Samson Erinfọlami Balogun Eletu, ti inagijẹ rẹ n jẹ Sam Larry, pe ki wọn maa lọ sile wọn.

Hundeyin ni, “Naira Marley ati Sam Larry ti kaju awọn nnkan ti wọn gbọdọ ko kalẹ lati gba beeli wọn. Tori ẹ, a ti tu wọn silẹ o.”

Ẹ oo ranti pe ṣaaju akoko yii ni ile-ẹjọ Majisreeti kan to fikalẹ siluu Yaba, l’Ekoo, ti faaye beeli silẹ fawọn afurasi ọdaran mejeeji yii lọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, lẹyin ti wọn ti sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun tijọba fi kan awọn lori iku Mohbad.

Lara awọn nnkan ti Adajọ kootu naa, Adeọla Ọlatunbọsun, paṣẹ pe wọn gbọdọ kaju rẹ ki wọn too le ri beeli gba ni pe, ki ọkọọkan wọn ni miliọnu lọna ogun, pẹlu ẹlẹrii mẹta mẹta ti wọn ni dukia to jọju l’Ekoo, wọn si gbọdọ ko iwe irinna wọn, iyẹn pasipọọtu kalẹ fun akọwe kootu.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, nileeṣẹ ọlọpaa Eko nawọ gan Sam Larry lati orileede Kenya to ti n bọ, ti wọn si sọ ọ sahaamọ fun ẹkunrẹrẹ iwadii lori ohun to mọ ati ipa to ko ninu awọn iṣẹlẹ idunkooko mọ ni kan to waye ki Mohbad too ku lojiji lẹni ọdun mẹtadinlọgbọn.

Ọjọ diẹ lẹyin naa, wọn tun fi pampẹ ofin mu Naira Marley, ni papakọ ofurufu Ikẹja, lasiko toun naa dari wale latilu oyinbo to wa.

Atigba naa lawọn mejeeji ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ lẹnu iwadii wọn.

Naira Marley yii ni ọga oloogbe Mohbad tẹlẹ, ileeṣẹ agborin-jade rẹ, Marlian Records, lo n gbe orin oloogbe yii jade ki aawọ too de laarin wọn, eyi to mu ki ọmọkunrin yii kuro nileeṣẹ naa.

Leave a Reply