Monisọla Saka
Owo iṣẹ ọjọ mejidinlogun pere nijọba apapọ san gẹgẹ bii owo iṣẹ awọn olukọ fasiti ti wọn wa labẹ akooso ẹgbẹ awọn olukọ ti wọn n pe ni ASUU, fun oṣu Kẹwaa ọdun yii.
Awọn olukọni ileewe giga fasiti atawọn agba ẹgbẹ ASUU ti wọn ba akọroyin PUNCH sọrọ ṣalaye pe aabọ lowo oṣu tijọba san fawọn.
Ọkan ninu awọn olukọ naa ṣalaye pe ‘iwọnba ọjọ ta a lo lẹnu iṣẹ lẹyin iyanṣẹlodi ni wọn fun wa. Aabọ lowo ti wọn san fun mi, koda inu n bi awọn yooku lọwọ bayii, niṣe ni wọn n da awọn igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa ti wọn fagi le iyanṣẹlodi ọhun lẹbi”.
Ọmọ ẹgbẹ ASUU mi-in toun naa fi kun un pe bọrọ ṣe ri niyẹn ṣalaye pe, “Bẹẹ ni, bo ṣe ri niyẹn. Aabọ owo ni wọn san fun mi, o da bii pe ijọba fẹẹ pa ẹgbẹ ajọṣepọ awọn eeyan run nilẹ yii ni ṣugbọn a o ni i gba, awa naa si ti ṣetan pẹlu wọn.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni ASUU fopin si iyanṣẹlodi oloṣu mẹjọ ti wọn ti gun le lati ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun ta a wa yii, lẹyin ti Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin nilẹ wa, Fẹmi Gbajabiamila, ba wọn da si i.