Stephen Ajagbe, Ilorin
Baba agbalagba ẹni ọgọta ọdun, Jerimiah Oyedokun, lọwọ ileeṣẹ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, ẹka tilu Kaiama, nipinlẹ Kwara, tẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, fẹsun fifi ipa ba ọmọ ọdun mẹsan-an kan ta a forukọ bo laṣiri laṣepọ.
Oyedokun, to n gbe lagboole Ilelọja, niluu Kaiama, lawọn obi ọmọ naa ba nibi to ti n ki ọmọ naa mọlẹ, ti wọn si figbe ta si araadugbo.
Kete ti wọn ra ọkunrin naa mu ni wọn wọ ọ lọ sọdọ awọn to wa niluu Kaiama, nibi tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.
Alukoro ileeṣẹ NSCDC nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afọlabi, ṣalaye pe aadọta naira ni afurasi naa fi tan ọmọde naa, to si fa oju rẹ mọra, ko too di pe o ki i mọlẹ.
Afọlabi ni, nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ. O fi kun un pe nigba tawọn fọrọ wa afurasi naa lẹnu wo, ọ jẹwọ pe loootọ loun ṣe bẹẹ, ṣugbọn ki wọn foju aanu wo oun.
O ni wọn ti gbe ọmọ naa lọ silewosan jẹnẹra tilu Kaiama, fun ayẹwo ati itọju.
O ni wọn ti gbe ẹjọ naa wa si olu ileeṣẹ NSCDC n’Ilọrin, lẹyin iwadii, awọn yoo wọ ọ lọ sile-ẹjọ.