Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Bi Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, ṣe n ṣayẹyẹ aadọta ọdun to gun ori itẹ awọn baba-nla rẹ, Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ti ṣapejuwe kabiesi naa gẹgẹ bii akanda ẹda kan ninu iran Oduduwa.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin fun aafin Ọọni, Moses Ọlafare, fi sita ni Arole Oduduwa ti ba Ọba Adeyẹmi dawọọ idunnu fun oore-ọfẹ to ri gba lati ri ọjọ oni ati lati jẹ apẹẹrẹ rere fun iran Oodua.
O ni “Ọba Adeyẹmi jẹ ori-ade ti tolori-tẹlẹmu n bu ọla fun lorileede Naijiria latari gbogbo igbesẹ rẹ lati gbe iṣe ati aṣa ilẹ Yoruba larugẹ. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ẹbun ẹmi gigun to fi jinnki rẹ lori itẹ awọn baba-nla rẹ.
“Ọba Lamidi jẹ ọba to ri aanu gba lọdọ Ọlọrun nitori kabiesi ti lanfaani lati ri ibu ati ooro orileede yii, iṣejọba awọn oyinbo amunisin ṣoju baba, o wa nibẹ lasiko ijọba ologun, nigba ti alagbada tun de, baba n ṣe ojuṣe rẹ nipa mimu ki ilẹ Yoruba wa niṣọkan.
“Iwuri nla ni oniruuru idagbasoke to de ba ilu Ọyọ lasiko Ọba Adeyẹmi jẹ fun mi, bẹẹ ni alaafia pipe to n jọba ni sakaani rẹ ko ṣee fẹnu sọ.”
Ọọni waa gbadura fun ẹmi gigun fun Alaafin, o ni orileede yii, paapaa, iran Yoruba, ṣi nilo ọgbọn rẹ lọpọlọpọ.