Aafaa atawọn ọmọ kewu ẹ meji ku sodo n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Titi di asiko yii ni ọpọ awọn ọmọ bibi ilu Ilọrin ṣi n daro gbajumọ aafaa kan to ku ninu ijamba mọto kan to ṣẹlẹ lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, Sheikh Abdulganiyu Nuraini, ti ọpọ eeyan mọ si Aafa Gani Aboto ati awọn ọmọ kewu rẹ meji, Aafa Azeez Ọmọẹkun ati Aafa Nurudeen.

Inu odo kan to wa ni Opopona Sobi, Akerebiata, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ni mọto wọn ko si lasiko ti wọn n dari bọ nibi ti wọn ti lọọ ṣe waasi ni ilu Minna, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Niger, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ ọsẹ to ṣẹṣẹ pari yii.

ALAROYE gbọ pe lalẹ ọjọ yii, arọọda ojo kan rọ, asiko ojo naa ni wọn n pada bọ nile. Ko sẹni to le sọ pato ohun to ṣokunfa bi mọto naa ṣe ko sodo, ṣugbọn awọn kan lo ṣee ṣe ko jẹ pe omi ti kun bo ori afara naa, wọn ko si rina daadaa nitori pe ilẹ ti tun ṣu. Eyi lo mu ki mọto wọn ko sodo ọhun, ti ko si ẹni to mọ si iṣẹlẹ buruku yii tori pe odo naa kun.

Ọsan ọjọ Abamẹta ti odo fa ni awọn to n gbe ni agbegbe Akerebiata ri taya mọto to n han ninu omi naa, ni wọn ba pe awọn panapana. Nigba ti wọn wọ inu odo naa ni wọn yọ oku aafaa atawọn ọmọ kewu rẹ mejeeji jade.

Mọto ayọkẹlẹ Toyota Corolla alawọ Gold ni mọto wọn ti nọmba rẹ jẹ Lagos APP 544 ET.

L’Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni wọn kirun si oku Aafa Aboto lara ninu ọgba ileewe Ansaru-Islam Primary School, Okekere, Ilọrin, ti wọn si gbe oku naa lọ siluu abinibi rẹ ni Aboto, nijọba ibilẹ Aṣa, nipinlẹ Kwara.

Leave a Reply