Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori to dunkooko iku mọ awọn agbofinro ti wọn wa lẹnu iṣẹ oojọ wọn, awọn ọlọpaa ti fi panpẹ ọba gbe Aafaa Ahmed Atidade, gbajumọ aafaa n’Ibadan.
Ọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28) yii lawọn ọlọpaa to n mojuto eto aabo oju popo da duro lati ṣayẹwo inu mọto rẹ gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe fawọn awakọ yooku to ti n gba iwaju wọn kọja. Ṣugbọn kaka ki aafaa onilawani nla yii fọwọsowọpọ pẹlu wọn, ija lo bẹrẹ si i ba awọn agbofinro naa ja, to si n leri fitafita pe pipa loun yoo pa wọn.
Ṣugbọn gbogbo bo ṣe leri ija si awọn ọlọpaa to, awọn onitọhun ko ba a janpata.
Ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin, Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, sọ pe
lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Keji, ọdun 2023 yii niṣẹlẹ ọhun waye loju ọna Ibadan s’Ekoo.
Ṣugbọn lọjọ karun-un lẹyin iṣẹlẹ naa, iyẹn lọjọ kẹsan-an, oṣu ọhun kan naa, lawọn agbofinro ba a lalejo, niṣe ni wọn kan deede yọ si i kulẹ nile ẹ n’Ibadan, ti wọn si gbe sọ satimọle.
Ko ju bii wakati meloo kan lọ sigba naa la gbọ pe wọn gbe Atidade lọ si kootu, nibi ti wọn gba pe ọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28) naa yoo ti jiya ẹṣẹ rẹ nilana ofin.
Ninu atẹjade mi-inti Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa lorileede yii, CSP Olumuyiwa Adejọbi, fi sita lo ti sọ pe “iṣẹ ilu lawọn agbofinro n ṣe lati ri i pe aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia gbogbo ọmọ orile-ede yii, a si ni lati maa pọn wọn le. Ileeṣẹ ọlọpaa lorileede yii ko waa le la oju wa silẹ ki awọn eeyan kan maa fi oju awọn ọlọpaa gbolẹ.
“Gbogbo ohun to ba gba la maa fun un lati daabo bo awọn ọlọpaa lọwọ iwọsi ti ẹnikẹni ba fẹẹ fi lọ wọn”.