Faith Adebọla
Gbogbo ẹyin tẹ ẹ ba lowo Naira nile, afi kẹ ẹ ma jafara bayii o, kẹẹ tete maa lọ paarọ ẹ si tuntun, tori Aarẹ Buhari ti foju awọn owo beba tuntun ti wọn paarọ awọn rẹ, ta a maa bẹrẹ si i na loṣu Keji, ọdun to n bọ.Latigba tijọba ti lawọn maa rẹ awọn owo beba ilẹ wa kan laro tuntun, pe awọn maa paarọ awọ wọn, lawọn eeyan ti n foju sọna lati mọ bi owo tuntun naa ṣe maa ri ati iru awọ to maa ni, ni bayii, Aarẹ Buhari ti ṣiṣọ loju eegun ọrọ yii o, wọn ti ṣafihan owo tuntun naa niluu Abuja.
Nibi ipade igbimọ apaṣẹ, eyi ti wọn maa n ṣe lọsọọsẹ, ni olori orileede wa ti ko aworan owo tuntun naa jade bii ọmọ ọjọ mẹjọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla yii.
Lasiko ti ipade naa n lọ lọwọ ni Buhari dide, ti Ọga agba banki apapọ ilẹ wa, Ọgbẹni Godwin Emefiele, naa si duro lẹgbẹẹ rẹ, n lawọn ọmọ igbimọ alakooso yooku ti wọn wa nipade naa ba dide, wọn n patẹwọ bi Buhari ṣe n fi aworan owo tuntun lede.
Mẹta lawọn owo naa, awọ buluu ni wọn ni ẹgbẹrun kan Naira, wan taosan (N1,000) gbe wọ bayii, awọ ewe, ginrin-in, to jọ eyi to wa lara tuẹnti Naira bayii ni wọn wọ fun ẹẹdẹgbẹta Naira, faifu ọndirẹẹdi, (N500) nigba ti igba Naira, iyẹn tuu ọndirẹdi Naira (N200) wọ awọ pupa rẹsurẹsu, o jọra pẹlu eyi to wa lara Naira mẹwaa lọwọlọwọ.
Oludamọran fun aarẹ lori iroyin ayelujara, Ọgbẹni Bashir Ahmad, lo ti kọkọ firoyin lede lori ikanni tuita (twitter) Aarẹ Muhammadu Buhari lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii pe awọn eeyan yoo mọ bowo yii ṣe ri lasiko ipade alakooso ti yoo waye lọjọ keji.
Amọ Aarẹ Buhari sọ pe owo tuntun naa ko ti i di nina o, awọn kan ṣi faworan ẹ lede ni o, o lo di ọjọ ki-in-ni, oṣu Keji, ọdun 2023 to n bọ, ki owo naa too gori atẹ, tawọn eeyan yoo si le maa lo o lẹnu kara-kata ati okoowo wọn gbogbo.
O ni igbesẹ yii pọn dandan, o si maa ṣaleekun agbara owo Naira ilẹ wa lọja agbaye, to ba ya.
Nipade naa, Emefiele ṣafikun si ọrọ ti Buhari sọ, o ni ki awọn banki atawọn alowolodu bii iyere kan ti wọn n beere pe ki banki apapọ sun gbedeke asiko ti wọn maa kasẹ owo atijọ naa nilẹ siwaju tete gbọkan kuro nibẹ, o ni ko sohun to jọ ọ, asiko tawọn ti fi lede ṣaaju naa lawọn maa kasẹ ẹ nilẹ, tori ẹ, o ni kawọn eeyan to lowo atijọ naa nile ma ṣe jafara, ki wọn lọ maa paarọ owo naa lawọn banki wọn gbogbo.