Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni Aarẹ Muhammadu Buhari pe iyawo olori ologun ile wa to ti doloogbe bayii, Fati Attahiru lori foonu. O ni oun pe e gẹgẹ bii aṣoju gbogbo awọn obinrin yooku ti awọn ọkọ wọn ku ninu ijamba ẹronpileeni to waye ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, nibi ti ọga ologun naa ati awọn alabaaṣiṣẹ-pọ pẹlu rẹ pẹlu awọn to wa baalu naa ti padanu ẹmi wọn.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Buhari lori eto iroyin, Garba Sheu fi sita ni Buhari ti ṣapejuwe Ibrahim Attairu gẹgẹ bii akọni to ṣiṣẹ takuntakun fun orileede rẹ titi doju iku.
O fi kun un pe ni gbogbo igba lawọn yoo ma mọ riri iṣẹ takuntakun ti awọn ṣọja wa n ṣe lati ri i pe a bọ kuro ninu ipenija gbogbo ti ilẹ wa n koju lai bẹru.
Aarẹ Buhari ni orileede yii ko ni i gbagbe ifira ẹni ji to tobi ju lọ ti awọn ologun to ku yii ṣe fun Naijiria. O waa rọ awọn iyawo wọn pe ki wọn ṣọfọ mọ niwọn, pe gbogbo ọrọ iwuri loriṣiiriṣii ti awọn eeyan kaakiri ẹya ni orileede yii n sọ nipa awọn akọni naa yẹ ko jẹ itunu fun wọn.
Arabinrin Attahiru waa dupẹ lọwọ Aarẹ fun pipe to pe wọn lati ba wọn kẹdun.
Yatọ si pipe ti Aarẹ Buhari pe iyawo ṣọja yii, iyawo Aarẹ pẹlu awọn ọmọ rẹ paapaa ti ṣabẹwo si iyawo ọga ṣọja patapata to ku yii.