Aare Muhammadu Buhari ti fi oṣu mẹta mi-in kun asiko ọga ọlọpaa patapata fun ilẹ wa, Muhammadu Adamu, to yẹ ko bẹrẹ ifẹyinti rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nitori asiko to yẹ ko fẹyinti lẹnu iṣẹ ti to.
Minisita fun ọrọ awọn ọlọpaa, Muhammad Dingyadi, lo kede ọrọ naa fawọn oniroyin niluu Abuja l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
O ni afikun oṣu mẹta yii ṣe pataki ki ijọba le baa raaye ṣeto to peye lati yan ẹni ti yoo rọpo rẹ.
Bẹ o ba gbagbe, ati bii ọsẹ kan nilẹ yii ni ariwo ti n lọ kaakiri ilẹ wa, tawọn eeyan si n beere pe ta ni yoo rọpo ọga awọn ọlọpaa ti asiko ifẹyinti rẹ ti to yii.
Bẹẹ lawọn kan ti n gbe e kiri pe ọkan ninu awọn ti wọn wa nipo igbakeji ọga ọlọpaa ni wọn yoo mu. Ṣugbọn ọrọ ya awọn eeyan lẹnu nigba ti wọn tun ri Adamu ninu aṣọ ọlọpaa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, to si jẹ pe oun lo waa pade Aarẹ Buhari ni papakọ ofurufu Abuja lasiko to de lati ibi to ti lọọ lo isinmi ọlọjọ mẹrin ni Daura ti i ṣe ilu abinibi rẹ.
Latigba naa lawọn eeyan ti n sọ pe o ṣee ṣe ki Aarẹ fi kun ọjọ ọkunrin yii gẹgẹ bii ọga ọlọpaa, ko too waa di pe ikede afikun oṣu mẹta yii waye.