Aarẹ Buhari ti tun n lọọ ri awọn dokita rẹ ni London

Lẹyin ipade eto aabo pajawiri ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe pẹlu awọn olori alaabo nilẹ wa niluu Abuja, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, yii, ọkunrin naa ti fi Naijiria silẹ, o ti tẹkọ leti lọ si London, o tun fẹẹ lọọ ri awọn dokita rẹ, ki wọn le yẹ ẹ ni gbogbo ara wo lati ri ipo ti ilera baba naa wa.

Gẹgẹ bi Oludamọran Buhari lori eto iroyin, Fẹmi Adeṣina, ṣe fi lede lori Twitter rẹ, o ni ọsẹ meji ni Buhari yoo lo lẹnu irinajo naa, nitori ọsẹ keji ninu oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni yoo too pada de.

Aimọye igba ni Aarẹ wa ti tẹkọ leti lọ siluu oyinbo fun itọju.

Leave a Reply