Faith Adebọla
Arẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, ti tun tẹ baaluu leti lọ si ilu London. Ọkunrin naa fẹẹ lọọ ri awọn dokita fun ayẹwo ara rẹ.
Ninu atẹjade ti Oludamọran rẹ lori eto iroyin, Fẹmi Adeṣina, fi sita lo ti ṣalaye ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pe Aarẹ n lọ siluu oyinbo lati lọọ ri awọn dokita rẹ, ireti si wa pe yoo pada silẹ wa ninu ọsẹ keji, oṣu keje, ọdun yii.
Bẹ o ba gbagbe, inu oṣu kẹta ọdun yii kan naa l’Aarẹ lọ siluu oyinbo kan naa fun ayẹwo.