Monisọla Saka
Aarẹ orilẹ-ede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti ni asiko ti to f’oun lati paarọ awọn kan ninu awọn eeyan to n ba oun ṣiṣẹ.
Aarẹ sọrọ yii di mimọ nipasẹ Oludamọran pataki lori iroyin rẹ, Bayọ Ọnanuga, nibi ipade oniroyin ti wọn ṣe l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, nile ijọba, l’Abuja.
Lasiko naa ni Tinubu rọ awọn minisita rẹ lati ma ṣe maa tiju to ba di ọrọ iroyin lati fọnrere iṣẹ wọn. O ni ki gbogbo awọn minisita nileeṣẹ ijọba kọọkan maa polongo iṣẹ ti wọn n ṣe, nitori bi wọn ṣe n ṣiṣẹ to, awọn ọmọ Naijiria ko mọ.
O ni, “Aarẹ ti fi erongba rẹ lati ṣe atunto awọn to n ba a ṣiṣẹ han. Mi o mọ boya ṣaaju ọjọ ayajọ ominira ilẹ wa ti yoo waye lọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹwaa ni, amọ mo mọ pe yoo ṣe e. Nnkan ti mo maa sọ niyi, amọ wọn ko ti i fun wa ni gbedeke igba ti yoo waye.
Nigba to n sọ awọn iṣẹ ribiribi ti Aarẹ ti gbe ṣe, o ni, “Aarẹ ti paṣẹ fun gbogbo awọn minisita rẹ nibi ipade ti wọn ṣe kẹyin pe ki wọn jade sigboro lati maa fọnrere awọn iṣẹ tijọba rẹ n ṣe. Ọpọlọpọ wọn ni wọn maa n tiju to ba di ọrọ oniroyin de, ki wọn jade si ori tẹlifiṣan tabi redio lati jẹ ki araalu mọ nipa gbogbo nnkan ti wọn n ṣe.
“Nitori ohun ti ọpọlọpọ araalu n ro ni pe ijọba yii ko ṣe nnkan kan, bẹẹ si ree, ijọba n ṣe gudugudu meje, oun yaaya mẹfa”.
Ọnanuga ni o ku si minisita kọọkan lọwọ lati maa polongo awọn iṣẹ ti wọn n ṣe nileeṣẹ wọn. O ni ki wọn jade gẹgẹ bi Aarẹ ti ṣe sọ, kawọn eeyan le mọ pe ijọba ko figba kankan dawọ iṣẹ duro.