Aarẹ Tinubu ko deede depo naa, awa la gbe e debẹ, ẹ jẹ ko lọ saa keji si i- Ọṣọba

Adewale Adeoye

Ọkan pata lara awọn oloṣelu ilẹ wa to tun ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Arẹmọ Oluṣẹgun Ọṣọba, ti sọ pe ki i ṣe agbara tabi ọgbọn inu Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lo fi depo pataki to wa yii, ṣugbọn awọn tawọn jẹ ojulowo oloṣelu ẹya Yoruba lorileede yii lawọn rọgba yi i ka, tawọn si ṣeranlọwọ ọhun fun un lati di aarẹ orileede yii.

Nibi eto pataki kan to waye lọjọ Abamẹta, Satide ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun yii nile itura igbalode kan ti wọn n pe ni Eko Hotel and Suite, to wa niluu Eko ni Arẹmọ Ọṣọba ti sọrọ naa di mimọ lasiko to n ba awọn oloṣelu bii tiẹ ti wọn jẹ ọmọ Yoruba sọrọ.

O ni, ‘Ki i ṣe Aarẹ Tinubu lo sọ ara rẹ di aarẹ orileede yii, awa ta a jẹ ọmọ Yoruba, ta a jẹ ojulowo oloṣelu ilẹ yii, la ṣepade laarin ara wa, ta a si fẹnu ko pe ka a ṣatilẹyin fun Tinubu ko le depo pataki ọhun. A ni saa ẹya Yoruba lo ku lati depo naa, Tinubu si lẹni ta a fẹnu ko le lori lati ṣatilẹyin fun lasiko naa.

Lasiko ipade pataki kan to waye lọdun 2007, la ṣepade laarin ara wa, asiko naa la fenuko pe ki Tinubu lọọ dupo pataki ọhun. Ni nnkan bii ọdun mẹtadinlogun sẹyin bayii la ṣepade naa laarin ara wa, ni kete ti Tinubu fipo gomina ipinlẹ Eko silẹ tan ni. Ipade pataki ta a ṣe nile Alhaji Hamsa nigba naa ni pe ko maa mura silẹ lati dupo aarẹ orileede yii laipẹ. Inu ipade naa la ti sọ fun un pe ko fi oṣelu ipinlẹ tabi ti agbegbe rẹ silẹ, ko maa mura fun ti gbogbogboo.

‘’Ọpọ igba lawọn oloṣelu ilẹ Yoruba maa n ri ijakulẹ lasiko ti wọn ba n dupo pataki bii ipo aarẹ orileede yii. Ọpọ awa ta a wa nibi la ṣatilẹyin fun Oloogbe Ọbafẹmi Awolọwọ nigba aye rẹ lati depo pataki naa, ṣugbọn ko bọ si i lọwọ. Bakan naa la gbiyanju gidi fun Oloogbe MKO Abiọla nigba aye rẹ pe ko di aarẹ orileede yii, ṣugbọn ko ja mọ oun naa lọwọ, koda, o fi ẹmi rẹ di i nigbẹyin ni. Wọn pa ọpọ lara awa ta a ni erongba gidi lọkan lati jẹ kiluu yii daa lasiko naa ni, ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba pe diẹ ninu awa ta a ja fitafita lasiko naa ṣi wa laye bayii, oju wa lo ṣe ti Tinubu fi di aarẹ orileede yii’’.

Fun idi eyi, Ọṣọba waa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC atawọn ẹya Yoruba gbogbo pe ki wọn gbaruku ti iṣakooso ijọba Tinubu lasiko yii, ko le ri saa keji ṣe pẹlu irọrun.

O ni bi wọn ba faaye gba a lẹẹkan si, a sọlu dẹrun fun kaluku wa ni, nitori pe oun nikan lo n ṣoju ẹya Yoruba nile loko bayii.

Leave a Reply