Adewale Adeoye
Ẹgbẹ agba ẹya Hausa kan ti wọn n pe ni ‘Northern Elders Forum’ (NEF) ti sọ pe ki i ṣohun to daa rara bi olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinbu, ṣe fẹẹ yan olori le awọn aṣofin agba orileede yii lọwọ gegẹ bo ṣe n gbiyanju lati ṣe bayii.
Ẹgbẹ naa sọ pe ṣe lo yẹ ki Aarẹ Tinubu faaye gba awọn aṣofin ọhun ki wọn dibo laarin ara wọn, ki wọn si yan olori to wu wọn funra wọn laijẹ pe ẹnikankan da sọrọ naa rara.
Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Ogbẹni Hakeem Baba-Ahmed, lo sọrọ ọhun di mimọ lakooko to n sọrọ lori ‘Channels TV’, niluu Abuja, lọjọ Iṣẹgun, Tuisdee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.
Ninu ọrọ rẹ lo ti sọ pe, inu ẹgbẹ NEF ko dun rara si bi ahesọ kan ṣe n lọ nigboro bayii pe Aarẹ Tinubu fẹẹ yan le awọn aṣofin agba ọhun lọwọ. O ni ṣe lo yẹ ki Tinubu jẹ ki ẹka ijọba ọhun da duro funra wọn ni, ki Aarẹ si faaye gba wọn lati ṣojuṣe wọn fawọn araalu to dibo yan wọn sipo naa.
Hakeem ni, ‘Igbagbọ awa ẹgbẹ NEF yii ni pe awọn aṣofin naa ki i ṣọmọde rara, wọn tojuu bọ daadaa, ṣe lo yẹ ko faaye gba wọn, ki wọn dibọ yan ẹni tabi olori ti wọn fẹ laarin ara wọn, ki i ṣohun to daa rara bi ọkunrin yii ba lọwọ ninu yiyan olori aṣofin, eyi le ṣakoba gidi fun eto iṣakooso wọn bi wọn ba bẹrẹ iṣẹ ilu ti wọn yan wọn fun.
‘‘Ohun ti ofin sọ ni pe awọn aṣofin agba naa lo gbọdọ yan olori laarin ara wọn laijẹ pe ẹnikankan da sorọ naa, ṣugbọn bi Aarẹ ba fi le gbiyanju lati da sọrọ naa, a jẹ pe ko fun wọn lafaani lati ṣojuṣe wọn niyẹn.
‘‘Igbagbo wa ninu ẹgbẹ NEF yii ni pe awon araalu ni wọn dibo yan awọn aṣofin naa pe ki wọn lọọ ṣoju wọn nileegbimọ, wọn nigbagbọ ninu wọn ni wọn ṣe dibo yan awọn oloṣelu yii pe ki wọn lọọ ṣoju awọn lọhun’’.
Ni ipari ọrọ rẹ, Hakeem loun gbagbọ pe Aarẹ Tinubu ko ni i ṣohun ti yoo tabuku ba ijọba rẹ lọna-kọna, ti yoo si faaye gba awọn aṣofin naa lati yan olori laarin ara wọn bi akoko ba to.