Adewale Adeoye
Gbogbo eto lo ti pari bayii lori bi Olori orile-ede Naijiria, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ṣe maa gbera lọ siluu China, lati lọọ ba olori orile-ede naa, Ọgbẹni Xi-Jinpin, sọrọ lori bi oko-owo to dan mọran ṣe maa waye laarin awọn orileede mejeeji naa. Ọsẹ akọkọ ninu oṣu to n bọ, iyẹn oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni Aarẹ Tinubu maa rin irin-ajo naa lọ sorileede China.
Oludamọran rẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Ajuri Ngelale, lo sọrọ ọhun di mimọ l’Abuja, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.
O ni yatọ si pe Aarẹ Tinubu maa ṣepade pataki pẹlu aarẹ orile-ede China, o tun maa lo asiko naa lati ba awọn ileeṣẹ bii: Huawei, ati ileese kan to n ṣe ojuna reluwe, iyẹn ‘China Rail and Construction Corporation’ (CRCC), sọrọ lori bi wọn ṣe maa wa sorileede Naijiria. Fun ti ileeṣẹ CRCC yii, wọn maa tọwọ bọwe adehun pẹlu ileeṣẹ naa lojuna lati ba wa ṣe aṣepari oju irin reluwe kan to lọ lati ilu Ibadan si Abuja ati Eko si Kano.
Atẹjade kan to fi sita nipa irin ajo naa lọ bayii pe, ‘’Lẹyin ti Olori orile-ede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ba pari ipade pataki to lọọ ṣe pẹlu olori orile-ede China tan, o maa ṣepade mi-in pẹlu awọn ileesẹ bii Huawei, CRCC atawọn ileesẹ mi-in, o si daju pe didun ni ọsan n sọ lọrọ ipade naa maa ja si.
‘’Yatọ sawọn ileeṣẹ ta a darukọ wọnyi, Aarẹ Tinubu maa tun ṣepade pẹlu awọn ileeṣẹ bii mẹwaa mi-in lori bi wọn ṣe maa waa da ileeṣẹ silẹ lorileede wa laipẹ yii.