Aarẹ Tinubu nikan lo laṣẹ ati kede afikun owo epo bẹntiroolu-Falana

Adewale Adeoye

Ilu mọ-ọn-ka lọọya ajafẹtọọ-ọmọniyan nni, Fẹmi Falana, ti sọ pe ki i ṣohun to tọna rara bi awọn alaṣẹ ileeṣẹ epo bẹntiroolu nilẹ wa, ‘Nigerian National Petroleum Company Limited’ (NNPCL) ilẹ wa ṣe kede afikun owo epo bẹntiroolu, eyi ti wọn ṣe lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.

O ni olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, nikan lo laṣẹ ọhun lọwọ, to si le ṣe iru ikede bẹẹ, niwọn igba ti ko ti i yan minisita fun ọro epo bẹntiroolu ilẹ wa.

Falana sọrọ ohun di mimọ lọjọ Ẹti,  Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lakooko to n ba awọn oniroyin Channels tẹlifiṣan niluu Eko.

O ni, ‘Ki i ṣohun to daa rara bi Alukoro ileeṣẹ NNPCL ilẹ wa, Ọgbẹni Garba-Deen Muhammed, ṣe kede pe awọn ti ṣafikun owo epo bẹntiroolu ọhun. O ni  ileeṣẹ yii ko laṣẹ rara labẹ ofin ilẹ wa, paapaa ju lọ niwọn igba ti wọn ki i ṣe ileeṣẹ ijọba apapọ ilẹ wa mọ, nitori ko fi bẹẹ siyatọ kankan laarin wọn atawọn ileeṣẹ elepo bẹntiroolu bii: Total, Shell tabi Exxon-Mobil rara. Aarẹ Tinubu nikan lo gbọdọ ṣekede iye tawọn araalu gbọdọ maa ra epo bẹntiroolu’’.

Leave a Reply