Monisọla Saka
Aarẹ orilẹ-ede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, atawọn igbimọ alaṣẹ ijọba apapọ, Federal Executive Council (FEC), ti yọ ileeṣẹ to n ri si ọrọ agbegbe Niger Delta (Niger Delta Ministry), ati ileeṣẹ to n ri si ọrọ ere idaraya (Ministry of Sports Development), kuro lara awọn ileeṣẹ ijọba apapọ orilẹ-ede yii.
Oludamọran Aarẹ lori eto iroyin, Bayọ Ọnanuga, lo kede ọrọ naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii. O ni lẹyin ipade ti Aarẹ ṣe pẹlu awọn igbimọ rẹ, (FEC), lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu yii, ni wọn fẹnu ko lori ọrọ naa.
“Aarẹ Tinubu atawọn igbimọ alaṣẹ ijọba apapọ ti wọgi le ileeṣẹ to n ri si ọrọ agbegbe Niger Delta ati ti idagbasoke ere idaraya.
“Ileeṣẹ ẹlẹkunjẹkun, ti yoo maa ri si idagbasoke gbogbo agbegbe ati ẹkun to wa lorilẹ-ede yii bii: idagbasoke ẹkùn Niger Delta, idagbasoke agbegbe Ariwa Iwọ oorun ilẹ yii, idagbasoke ẹkun Guusu Iwọ Oorun ati ileeṣẹ idagbasoke Ariwa Ila Oorun”.
O fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo ojuṣe ileeṣẹ to n ri si idagbasoke ere idaraya (Ministry of Sports Development), yoo di ti ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ere idaraya ni Naijiria (National Sports Commission), ti wọn yoo si maa ṣe kokaari gbogbo ohun to ba ti jẹ mọ ọrọ ere idaraya lorilẹ-ede yii.
O fi kun un pe igbimọ naa tun buwọ lu aba lati jan ileeṣẹ to n ri si ọrọ ibudo igbafẹ atawọn nnkan iṣẹmbaye (Ministry of Tourism), papọ mọ ileeṣẹ ijọba to n ri si aṣa ati eto ọrọ aje atinuda, (Ministry of Culture and Creative Economy), lati di ẹyọ kan ṣoṣo.