Aarẹ Tunubu ṣedaro awọn to ku nibi ijamba ọkọ oju omi ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa yii, ni Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, kẹdun pẹlu awọn eeyan ipinlẹ Kwara, lori ijamba ọkọ oju omi to fẹmi ọpọ arinrin-ajo ṣofo nipinlẹ naa loru ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nijọba ibilẹ Patigi.

Ninu atẹjade kan to jade lati ọdọ Abiọdun Ọladunjoye, to jẹ adari iroyin rẹ, ni Tinubu ti sọ pe pẹlu ibanujẹ ọkan ni oun fi gbọ iroyin iṣẹlẹ agbọ-bomi-loju to ṣẹlẹ nipinlẹ Kwara, nibi ti ọkọ oju omi ti fi ọpọ ẹmi awọn to n dari bọ lati ibi ayẹyẹ igbeyawo ṣofo.

Aarẹ ni oun kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi ati ọrẹ awọn to padanu ẹmi wọn nibi ajalu ọhun. Bakan naa lo tun kẹdun pẹlu ijọba ati olugbe ipinlẹ Kwara, o gbadura pe ki Ọlọrun rọ gbogbo wọn loju lati fara gba adanwo naa.

Bakan naa, o rọ ijọba Kwara, atawọn ajọ tọrọ kan ki wọn ṣewadii ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ijamba naa. O ni iṣejọba oun yoo wo gbogbo awọn ipenija tawọn ọkọ to n rin lori omi lorile-ede yii n koju lati wa ọna abayọ si awọn iṣoro naa, ti aabo yoo si wa fun gbogbo awọn arinrin-ajo ori omi.

O tẹsiwaju pe ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Kwara, yoo ṣe iwadii ohun to sokunfa ijamba naa, ti wọn yoo si ṣe iranwọ to ba yẹ fun awọn to fara kaasa nibi iṣẹlẹ naa.

 

Leave a Reply