Aarẹ ilẹ wa, Ọgagun Muhammadu Buhari, ti balẹ si Bamako, lorileede Mali, nibi ti oun atawọn olori ilẹ Afrika mi-in yoo ti pade lati pẹtu si wahala to n lọ lorileede naa.
Ọpọ eeyan lo ti n fi aidunnu wọn han si igbeṣẹ Aarẹ yii. Wọn ni okunrin naa ko ran wahala to n lọ lorileede rẹ, eyi to n lọ ni ilẹ mi-in lo n lọọ ba wọn pari. Wọn ni ile rẹ ti i ṣe Naijiria ko toro, eyi lo si yẹ ko kọkọ mojuto ko too sọ pe ohun maa lọọ ba awọn ẹlomi-in pari ija.
Eyi to ya awọn eeyan to ri aworan Aarẹ Buhari lẹnu ni ibomu ti baba naa fi bo imu rẹ pinpin. Eyi ni igba akọkọ ti ọkunrin naa yoo lo ibomu yii latigba ti arun Koronafairọọsi ti gbode.
Ni gbogbo igba ti awọn eeyan ba ṣabẹwo si Buhari, tabi to ba n ba awọn ọmọ orileede yii sọrọ, ọkunbrin naa ki i lo ibomu, eyi ti awọn eeyan kọminu si, ti wọn si n beere ni gbogbo igba pe ki lo de ti Aarẹ wa ko bomu.
O jọ pe ile nikan ni Aarẹ Buhari ki i ti i bomu o. Baba naa bo imu rẹ pinpin ni ni Bamako.
Ẹ gbọ, ṣe ẹyin fara mọ bi Buhari ṣe lọọ pari ija ni Bamako?