Aarin ede gbigbẹ ni Peter tọju igbo to fẹẹ gbe sọda soke okun si tọwọ fi tẹ ẹ

Faith Adebọla

Yooba bọ, wọn lohun to ba jọhun la a fi we’hun, eepo ẹpa lo jọ posi ẹliri, imi adigbọnranku si jọ t’alabahun, boya owe yii ni afurasi ọdaran ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Peter Ugwu Tochukwu, ronu kan to fi dọgbọn buruku kan lasiko to fẹẹ rin irinajo lọ sorileede Omar. Niṣe lo di ọpọlọpọ egboogi oloro ti wọn n pe ni skunk, iyẹn awọn ewe gbigbẹ bii igbo atawọn egboogi oloro gbigbẹ mi-in sinu lailọọnu dudu kan, lo ba gbe ẹru ofin ọhun saarin ọpọlọpọ ede gbigbẹ, o pọn gbogbo ẹ mọran-in-mọran-in debii pe ko sẹni to le fura pe ki i ṣe ede gbigbẹ nikan lo wa ninu ọra naa, diẹ lo si ku ko wọ baaluu ni papakọ ofurufu Muritala Mohammed, to wa n’Ikẹja, l’Ekoo, kọwọ too tẹ ẹ.

Alukoro ileeṣẹ ajọ to gbogun ti lilo, gbigbe ati ṣiṣe okoowo egboogi oloro nilẹ wa, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, sọ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an yii, pe, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu yii lọwọ palabi afurasi ọdaran yii segi lasiko to fẹẹ wọ baaluu n’Ikẹja.

O ni ọkọ ofurufu Qatar Airways, to n lọ sorileede Omar, ni Peter, ọmọ bibi ijọba ibilẹ Iziugo, nipinlẹ Enugu, fẹẹ wọ, orileede naa lo n gbiyanju ati gbe egboogi oloro to fi ede gbigbe bo laṣiiiri lọ. Nigba ti wọn si ṣodiwọn ẹru ofin ọhun, o fẹrẹ to iwọn kilogiraamu mẹjọ (7.50 kg). Nigba ti wọn tun tu ẹru ọhun daadaa ni wọn tun ri ewe ewuro gbigbẹ to fi yi skunk yii.

Babafẹmi ni awọn ti taari afurasi ọdaran yii sakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ NDLEA lati tubọ tọpinpin ẹ daadaa, ki wọn si le foju rẹ bale-ẹjọ lẹyin iwadii.

Leave a Reply