Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bi Rafiat Wahab, ọmọbinrin kan to ni ṣọọbu ti wọn ti n fowo ranṣẹ tabi gba owo ti ko ba pọ pupọ (POS Operator), ṣe n ṣilẹkun ṣọọbu ẹ lọjọ kẹrinleogun, oṣu kẹrin, ọdun 2021, ọwọ ọkunrin kan to ti n ṣọ ọ tipẹ, Ogunnaike Philips, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, lo ṣilẹkun ọhun si. Iyẹn ni ṣọọbu ẹ to wa ni Adehun, Rounder, l’Abẹokuta.
Niṣe ni Philips yọ ada si Rafia, to ni ko gbe baagi owo to fi n ṣowo le oun lọwọ, ai jẹ bẹẹ,oun yoo ṣa a pa ni.
Ibẹru mu Rafiat, o gbe baagi fun Ogunnaike, niyẹn ba sare jade, lo n sa lọ. Ṣugbọn nigba ti ori rẹ yoo ta ko o, nibi to ti n ṣọṣẹ ọhun lọwọ lawọn kan ti ta ọlọpaa lolobo, ko si ti i rin jinna laduugbo naa tọwọ fi tẹ ẹ.
Kawọn ọlọpaa too de lawọn kan ti mu un silẹ, wọn lu u bii ko ku, wọn tun fi ada rẹ to fi halẹ mọ oniṣọọbu naa ṣa a lapa, iyẹn si jinlẹ gidi.
Nibi ti Philips ti n jiya rẹ yii lọwọ ni Isaiah Onifade naa ti waa woran rẹ, lo ba n sọ fawọn araadugbo pe ki wọn mu un daadaa o, ole ni, bo ṣe n jale kiri niyẹn, ki wọn ma jẹ ko pẹ ki wọn too pa a.
Ohun ti Isaiah sọ yii bi Ogunnaike ninu, nigba naa lo ni ki wọn jẹ koun sọrọ kan fun wọn, ki wọn ma ti i lu oun pa.
Ogunnaike, nigba to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ naa fun ALAROYE ni Eleweeran, l’Abẹokuta, l’Ọjọbọ to kọja yii, sọ pe boun ṣe ri Isaiah to n sọ pe kawọn araadugbo mu oun daadaa loun jẹwọ fun wọn pe awọn jọ n jale ni.
O ni oun ko mọ Rafiat tẹlẹ, Isaiah Onifade toun mu bii aburo laduugbo lo sọ foun pe owo buruku wa lọwọ obinrin to n ṣe POS naa, pe koun lọọ fi ada halẹ mọ ọn.
O tẹsiwaju pe Isaiah ko tẹle oun wọnu ṣọọbu naa ni, ṣugbọn o duro si itosi ibẹ, o si n ṣọ bi nnkan ṣe n lọ.
O ni nigba tọwọ palaba oun waa segi tan, to waa jẹ Isaiah, ẹni ọdun mejilelogun, toun mu bii aburo lo waa n ta ko oun loju awọn eeyan, o lohun to jẹ koun jẹwọ fun wọn pe awọn jọ mọ nipa ẹ niyẹn, ni wọn ba mu Isaiah Onifade naa.
Nigba to n ṣalaye tiẹ f’ALAROYE, Isaiah sọ pe oun ti fun Ogunnaike lọwọ lori bi yoo ṣe ṣiṣẹ naa tẹlẹ, oun si ti pada sile lẹyin igba toun ti ba a ṣọ agbegbe naa diẹ.
O ni nibi toun ti n fọṣọ lọwọ loun ti gbọ pe wọn ti mu un, toun si lọọ wo o, bo ṣe sọ fun wọn pe awọn jọ mọ nipa ẹ ni niyẹn.
Owo to din diẹ lẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ( 238, 850) lawọn ọlọpaa sọ pe o wa ninu baagi Rafia ti Ogunnaike gba, bẹẹ ni wọn ri ẹrọ POS to fi n ṣiṣẹ naa gba lọwọ ọdaran to ja a lole yii pẹlu.
Bi kootu ba ti bẹrẹ iṣẹ pada, Ogunnaike ati Onifade yoo foju bale-ẹjọ bawọn ọlọpaa ṣe wi.