‘Aaye Sunday Sunday Igboho ki i ṣe ọgba ẹwọn, eyi lohun to fa a to fi wa nibẹ’

Adefunkẹ Adebiyi

Ọkan ninu awọn agbẹjọro ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Dokita Falọla, ti sọ pe aaye Sunday Igboho ki i ṣe ọgba ẹwọn, nitori ki i ṣe ọdaran, ko jale, bẹẹ ni ko gba iyawo oniyawo, ohun to si ṣe lati gba awọn eeyan rẹ silẹ gẹgẹ bii ajijagbara tọna, eyi ki i ṣe ẹṣẹ.

O sọrọ yii nigba to n ba ALAROYE sọrọ lorileede Olominira Benin ti awọn akọroyin wa ti ṣabẹwo si i.

Ijọba Benin ko ni awijare nnkan tabi ẹsẹ kan to ṣẹ. Ki wọn too gbe e debẹ, wọn ṣaa gbọdọ wa nnkan kan si i lẹsẹ ki wọn too gbe e lọ si ọgba ẹwọn. Mi o le maa sọ gbogbo rẹ ninu afẹfẹ. Ṣugbọn gbogbo ipa ni a ṣa lati ri i pe itọju to peye wa fun un ni ọgba ẹwọn to wa. Ko jẹun to daa, ki alaafia wa fun un, ki ohun gbogbo si wa ni itura fun un.

Leave a Reply