Abamọ nla gbaa nireti ọtun tijọba Aarẹ Tinubu polongo fawọn ọmọ Naijiria-Yusuf

Adewale Adeoye

Okan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ ‘Northern Elders Forum’ (NEF) l’Oke-Ọya, Ọjọgbọn Usman Yusuf, ti bẹnu atẹ lu iṣejọba Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, pe ifasẹyin ati akoba nla gbaa ni ‘Ireti-Ọtun’ tijọba rẹ n polongo fawọn ọmọ orileede yii jẹ ni gbogbo ọna. O ni dipo ki ara tu wọn gbẹdẹ, ṣe ni gbogbo nnkan le koko bii oju ẹja fun wọn, tiluu ko si rọgbọ mọ lasiko iṣejọba Tinubu.

Ọjọgbon Usman to ti figba kan jẹ alakooso ẹka nileeṣẹ ijọba apapọ kan to n ri sọrọ mada-n-dafo lori eto ilera, ‘National Health Insurance Scheme’ NHIS lo sọrọ ọhun di mimọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, lasiko tawọn oniroyin ileeṣẹ  Channel tẹlifiṣan n fọrọ wa a lẹnu wo.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘Kaka ki iṣakooso ijọba Tinubu bomi itura sara awọn araalu, ṣe lo n ko inira ati ipọnju ba wọn, iṣakooso ijọba rẹ fọdun kan ko dara rara, ṣe ni gbogbo nnkan le koko bii oju ẹja fawọn ọmọ Naijiria.

‘‘Awọn araalu ti sọ ireti nu patapata, inu mi maa n bajẹ ni nigba ti mo ba ri i bawọn araalu ṣe n to lati gba agolo irẹsi kan lọwọ ijọba, eyi ti wọn n pe ni ‘ounjẹ iranwọ’. O daju pe ‘Ireti-Ọtun’ tijọba Tinubu polongo fawọn araalu ti di asan mọ wọn lọwọ bayii, ko si ireti ọtun kankan fawọn araalu mọ. Iṣakooso ijọba Tinubu fun ọdun kan ti mu ifasẹyin nla bawọn araalu yii gidi.

Lati ọsẹ to n bọ, wọn yoo maa parọ fawọn araalu iṣẹ ti wọn ti gbe ṣe lọdun kan ti wọn ti gbajọba orileede yii. Bẹẹ kẹ, ọkẹ aimọye awọn araalu ni iṣakooso ijọba wọn ti ṣakooba nla fun. Aimọye awọn ọmọọleewe ni iṣakooso ijọba wọn ti le danu kuro lẹnu ẹkọ, nitori ti awọn obi wọn ko le sanwo ileewe wọn mọ.

Ọjọgbọn Usman ṣapejuwe ikọ alabaaṣiṣẹ pọ Tinubu gẹgẹ bii ‘agba-lọwọ-meeri’. Ti wọn ko loye kikun nipa eto iṣejọba ati ọrọ aje orileede yii rara.

 

Leave a Reply