Abass ta mọto fun Emmanuel, bo ṣe gbowo tan lo gun un labẹrẹ pa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ninu oṣu Keje, ọdun yii, to lọ sipinlẹ Edo lo ṣalaabapade Emmanuel Oyioba to n fi mọto kan ṣe tasin kaakiri. Nibẹ ni ọrẹ wọn ti wọ, to si jẹ pe Emmanuel lo gbe Abbas kaakiri fun gbogbo ọjọ to lo nibẹ.

Nigba to fẹẹ kuro ni Edo, o ṣeleri lati maa pe dẹrẹba yii loorekoore, wọn si jọ gba nọmba ara wọn.

Ninu oṣu Kẹjọ to kọja yii ni Abbas pe ọrẹ rẹ yii pe oun fẹẹ ta mọto Toyota Camry ti oun n lo, wọn si jọ fẹnu ko pe ko gbe e wa si Edo lati yẹ ẹ wo.

Lẹyin ti Emmanuel ṣayẹwo mọto to ni nọmba YAB 368 CN naa, to si tẹ ẹ lọrun lo san miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna irinwo Naira (#1.4m) fun Abbas.

Ṣugbọn lẹyin to sanwo tan, ko kuro ni Edo, o ṣi n fara pa ọrẹ rẹ. Nigba to di ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, lo lo anfaani naa lati gun Emmanuel ni abẹrẹ iku, o wọ oku rẹ ju sinu igbo kan, o si gbe mọto Camry naa sa lọ.

Nigba ti aṣiri tu, awọn ọlọpaa ipinlẹ Edo fi ẹrọ igbalode wadii ibi ti mọto naa wa, o si di mimọ pe o ti de agbegbe ipinlẹ Ọṣun, bayii ni wọn pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, ti awọn naa si bẹrẹ igbesẹ kiakia.

Oju-ọna Ejigbo si Ogbomọṣọ ni ọwọ ti tẹ Abbas, o si jẹwọ pe loootọ niṣẹlẹ naa. Kọmiṣanna ọlọpaa, Wale Ọlọkọde, ti ṣeleri pe laipẹ ni yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply