Akinkanju ọlọpaa ti wọn ṣẹṣẹ jawee gbele-ẹ fun lẹnu iṣẹ nni, Abba Kyari, ti yọju si igbimọ olugbẹjọ lọdọ awọn ọlọpaa l’Abuja, lori ẹsun owo buruku ti Hushpuppi, agba Yahoo ni Dubai, sọ pe o gba lọwọ oun.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, la gbọ pe igbimọ olugbẹjọ yii bẹrẹ ijokoo wọn niluu Abuja, Igbakeji ọga ọlọpaa pata, Joseph Egbunike, lo si jẹ alaga nibẹ. Ṣugbọn ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹta, oṣu kẹjọ yii, ni Kyari foju han lọhun-un lẹyin ti wọn pe e, ohun to si sọ fun wọn ni pe ọwọ oun mọ lori ẹsun ti wọn fi kan oun naa, o ni irọ gbuu ni agba Yahoo naa pa mọ oun.
‘Special Investigation Panel’ ni wọn n pe igbimọ ti Kyari lọọ jẹjọ lọdọ wọn yii. Iyẹn Igbimọ Oluwadii to jẹ Akanṣe. Awọn ni wọn n ri si ẹsun bii eyi laarin awọn ọlọpaa ilẹ wa. Esi ti Kyari ba si fun wọn ni wọn yoo fi ranṣẹ si FBI, iyẹn awọn ọlọpaa agbaye, ẹka ti Amẹrikaa ti wọn ti ni ki Kyari waa ṣalaye ara ẹ fawọn.
Ṣe Ramọn Abass tawọn eeyan mọ si Huspuppi lo lo jẹwọ fun wọn pe oun fun Kyari lowo lati ti ọkan ninu awọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ lu oniṣowo Dubai kan ni jibiti, Vincent Kelly Chibuzor, mọle nitori o fẹẹ ko ba oun lọdọ ọkunrin tawọn n lu ni jibiti naa.
Fun Abba Kyari ti wọn waa fi jẹ olori awọn ọlọpaa to n fi laakaye ṣiṣe ọtẹlẹmuye lati ṣe iru nnkan bẹẹ, iwa to lodi sofin gbaa ni. Ohun to sọ ọlọpaa agba yii di ẹni ti wọn ni ko yẹba diẹ lẹnu iṣẹ na, titi ti iwadii ti wọn n ṣe yii yoo fi pari ree.
Ṣugbọn Abba ni ọwọ oun mẹwẹẹwa ree, ọmọ loun yoo fi gbe jo.