Faith Adebọla, Eko
Ti wọn ba n daṣa pe ara ija leyin wa, ọrọ naa ki i ṣe irọ, tori eyin ni Tasuru Abdullahi, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn yii, fi da batani si obinrin ti wọn jọ n ja lara, ṣugbọn ki i ṣe ara lasan, ori ọmu Nkechi Anosike ni Abdullahi ge jẹ, o tun gbe kinni to ja si i lẹnu naa mi, lo ba balẹ sile-ẹjọ.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ni iṣẹlẹ agbọrẹrin-in yii waye nile-ẹjọ Majisreeti to n gbọ ẹsun iwa ọdaran abẹle, eyi to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko.
Awọn ọlọpaa ni wọn wọ ọkunrin naa lọ si kootu, ẹsun iwa ọdaran ni wọn fi kan an, wọn tun lo jẹbi ifipa bani lo pọ, tori ẹya ara ibalopọ ẹni ẹlẹni lo ṣakọlu si.
Agbefọba, Inpẹkitọ Kenrich Nomayo, ṣalaye niwaju adajọ pe iwadii tawọn ṣe fihan pe ija wẹrẹ kan lo bẹ silẹ laarin wọn lọjọ kejilelogun, oṣu kẹjọ, ta a wa yii, l’Opopona Muphi, lagbegbe Ọrẹgun si Ikẹja, laarin Abdullahi, aja-feyin-ja, ati Abilekọ Nkechi. Ko si pẹ tija naa fi di nla, lawọn mejeeji ba n wọdimu.
O ni nibi ti wọn ti n se kitakita, ti wọn n lu ara wọn, nigba ti Abdullahi ko mọ eyi ti yoo ṣe mọ, niṣe lo ja bọtinni ẹwu tobinrin naa wọ, lo ba deyin de ori ọmu rẹ, o si ge e jẹ titi ti awọ naa fi ja si i lẹnu, o tun gbe e mi.
Agbefọba ni pẹlu ẹjẹ ṣoroṣoro ni wọn gbe obinrin naa wa si teṣan ọlọpaa Area ‘F’, n’Ikẹja, lati fẹjọ sun, awọn bọisi adugbo ko si jẹ ki Abdullahi lọ, wọn wọ oun naa de teṣan, lawọn ọlọpaa ba ju u si gbaga, wọn si gbe Nkechi lọ sọsibitu fun itọju.
O ni iwa ti afurasi ọdaran naa hu ta ko isọri ojilerugba ati marun-un, ọtalerugba ati mẹta ninu iwe ofin iwa ọdaran tọdun 2015 ti wọn n lo nipinlẹ Eko.
Ṣugbọn afurasi ọdaran ni oun ko jẹbi pẹlu alaye.
Adajọ Elizabeth Adeọla ni ko sọ alaye rẹ di ọjọ mi-in, ṣugbọn o yọnda beeli fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira, oniduuro meji ti ọkọọkan wọn ni iye owo kan naa ninu akaunti wọn, ti wọn niṣẹ gidi lọwọ, ti wọn niwee-ẹri sisan owo-ori wọn funjọba fun ọdun meji sẹyin, ti wọn si ni dukia to jọju lagbegbe kootu naa.
Aijẹ bẹẹ, Adajọ ni ki wọn da afurasi ọdaran ọhun pada si ahaamọ ẹwọn titi di ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹsan-an, ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.