Florence Babaṣọla
Abdullahi Salisu, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ti n kawọ pọnyin ni kootu Majisreeti kan niluu Ileefẹ lori ẹsun pe o lu iya arugbo, ẹni ọgọrun-un ọdun nilukulu.
Ṣe ni Abdullahi atawọn ẹgbẹ rẹ ti wọn ti sa lọ bayii lọ sile iya naa to wa lagbegbe Sabo, niluu Ileefẹ, lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii, laago mẹrin irọlẹ ku iṣẹju mẹẹẹdogun.
Lẹyin ti wọn lu yii tan, wọn tun gba ọkan lara awọn ọmọ rẹ, Uman Adamu, leti.
Inspẹkitọ Sunday Ọsanyintuyi to gbe Abdullahi wa si kootu ṣalaye pe olujẹjọ nikan ni ọwọ tẹ lara awọn ti wọn jọ ṣiṣẹ ibi ọhun. O ni iwa to hu ọhun ni ijiya nla, bẹẹ lo lodi si ofin ọtalelọọọdunrun-un o din marun-un (355) ati okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din mẹrin (516) iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.
Nigba ti wọn ka ẹsun mejeeji to ni i ṣe pẹlu igbimọ-pọ huwa buburu ati ṣiṣe ikọlu si olujẹjọ leti, o ni oun ko jẹbi wọn.
Agbẹjọro olujẹjọ, Leke Dada, rọ kootu lati faaye beeli silẹ fun un pẹlu ileri pe yoo maa wa si kootu ni gbogbo igba fun igbẹjọ rẹ.
Adajọ A. A. Ayẹni fun olujẹjọ ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira (#100,000) ati oniduuro meji ni iye kan naa.
Ko too di pe o sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, Ayẹni paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa mọ adirẹsi awọn oniduuro mejeeji, ki wọn si fi fọto pelebe mẹta-mẹta silẹ.