Abdulrazaq fẹẹ ṣe gomina Kwara lẹẹkan si i, awọn igun Lai Muhammed ni ko sohun to jọ ọ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ẹgbẹ oṣelu APC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti sọ pe Gomina Abdulrazak yoo dije dupo lẹẹkan si i lọdun 2023, sugbọn awọn igun Minisita fun eto ibanisọrọ nilẹ wa, Lai Muhammed, sọ pe ala ti ko le ṣẹ ni, wọn ni gomina naa ko yẹ loye mọ.

Nigba ti alaga ẹgbẹ naa ni Kwara, Ọmọọba Sunday Fagbemi, n sọrọ lopin ọsẹ yii nijọba ibilẹ Moro, nibi ti wọn ti n pẹtu sọkan awọn to n fapa janu ninu ẹgbẹ ọhun. O rọ awọn eniyan ẹkun idibo ariwa ipinlẹ naa pe ki wọn jẹ ki Abdulrazak lo ọdun mẹjọ rẹ ko pe, ko ṣe ẹẹkan si i titi di ọdun 2027, nitori awọn eeyan agbegbe naa ni o kan.

Sugbọn awọn ti igun Lai Muhammed fariga, wọn tutọ soke, wọn foju gba a, wọn ni ko le ṣee ṣe ki Gomina Abdulrazak lọ lẹẹkan si i tori pe ko tọ si ipo naa mọ. Ẹni to jẹ ọkan gboogi ninu igun Lai to n fapa janu, Ọgbẹni Akogun Iyiọla Oyedepo, to sọrọ nibi ipade naa ni agbọnrin eṣin ni gomina yii n jẹ lọbẹ. O ni ko sohun to jọ pe Gomina Abdulrazak yoo ṣe ẹẹkan si i.

Leave a Reply