Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ keji ti Minisita fun ibanisọrọ ati aṣa nilẹ yii, Lai Muhammed, pe Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, ni ‘one chance’ ni awọn eekan ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ naa ti n jade, ti wọn si n sọ ogulutu ọrọ si Lai Muhammed, eyi lo mu ki awọn Sẹnetọ lẹkun mẹtẹẹta ipinlẹ Kwara, Sẹnetọ Lọla Ashiru (Guusu Kwara), Ibrahim Oloriẹgbẹ (Arin Gbungbun Kwara) ati Umar Sadiq (Ariwa Kwara) ba awọn oniroyin sọrọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ti wọn si ni gomina Abdulrazaq ni awọn mọ gẹgẹ bii adari ẹgbẹ oṣẹlu Onitẹsiwaju, APC, nipinlẹ Kwara, wọn ni ariwo lasan ni Lai n pa.
Wọn jẹ ko di mimọ pe, gbogbo owo ti awọn ri lasiko ìpolongo idibo ọdun 2019, ni awọn na bo ti tọ ati bo ti yẹ, labẹ idari Gomina Abdulrazaq to n dije dupo gẹgẹ bii gomina nigba naa lọhun-un.
Ashiru ni ipa malegbagbe ni gomina ṣi n ko lọwọlọwọ bayii nipa idagbasoke ilu pẹlu awọn ohun amayedẹrun to ti ṣe. Ṣugbọn oun ko ni i sọrọ lori nnkan ti Lai Muhammed sọ lori owo ipolongo idibo ọdun 2019, tori pe o ti di ọrọ ọdun meji sẹyin, igba yẹn ti re kọja, igba ọtun si ni awọn wa bayii.
Oloriẹgbẹ ni tiẹ so pe awọn ti gbaju mọ akọmọna “O TO GẸ” ti awọn fi dori ipo, bakan naa lawọn jọ n ṣiṣẹ pọ ni, awọn o ya ara awọn lọtọọtọ, o fi kun un pe eto iforukọ ọmọ ẹgbẹ silẹ yoo bẹrẹ pada ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje ti a wa yii.
Sodiq ni ko ni bojumu ki ẹgbẹ pin yẹlẹyẹlẹ, lẹyin ti ẹgbẹ APC ja ija ominira tan, ti wọn gba agbara.