Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Ọlọrun nikan lo mọ ohun to faja to bẹẹ laarin ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji yii, Obinna Kalu, ati obinrin kan ti wọn jọ n gbele torukọ tiẹ n jẹ Adijat Balogun, to fi di pe maanu yii wọle tọ ọ nigba tiyẹn n sun oorun ọsan lọwọ lọjọ kẹrinla, oṣu kẹta yii, to si yinbọn mọ ọn lẹgbẹẹ otun nile wọn to wa ni Ilupeju /Sabo, l’Abẹokuta.
Lasiko ti a n kọroyin yii,ọsibitu FMC, l’Abẹokuta, ni Adijat wa to ti n gbatọju látàrí ibọn ti Kalu yin mọ ọn.
Ẹnikan ti wón pe orúkọ ẹ ni Ọlayiwọla Kareem lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Sabo/Ilupeju, l’Abẹokuta, pe Kalu to jẹ ayalegbe bii Adijat, yọ wọ yaara obinrin naa lọsan-an ọjọ kẹrinla, oṣu kẹta yii, nígba tobìnrin naa n sun lọwọ, o si yinbọn fun un lẹgbẹẹ ọtun loju oorun to wa.
Kia lawọn ọlọpaa tẹle e lọ sile naa bi Alukoro wọn, DSP AbimbọlaOyeyẹmi, ṣe wi, ti wọn gbe Adija lọ sọsibitu jẹnẹra to wa n’Ijaye, kawọn iyẹn too ni ki wọn maa gbe e lọ si FMC, Idi-Aba.
Bi Kalu ṣe pitu ọwọ ẹ tan lo sa kuro nile, wọn, gbogbo ẹru ẹ to ṣee ko pata lo ko, o tilẹkun yara rẹ, o si lọọ faraṣoko sibi kan.
Iwadii ati itọpinpin awọn ọlọpaa lo jẹ ki wọn ri i mu lọjọ kẹta iṣẹlẹ naa, ohun to si sọ fun wọn ni pe oun ko mọ nnkan kan nipa ibọn yinyin ohun.
Nigba tawọn ọlọpaa beere lọwọ ẹ pe ki lo waa de to fi sa kuro nile, nigba naa ni Kalu ko ri nnkan kan sọ mọ́, o kan n wolẹ ni.
Ẹka to n ri si ipaniyan nipinlẹ Ogun ni wọn taari ẹ si bayii, ki wọn gbe e lọ si kootu lo ku gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe sọ.