Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Kootu kọkọ-kọkọ to wa lagbegbe Wáráh, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ni obinrin ẹni ọdun marundinlogoji kan, Naimọt Aminullahi, mu ẹjọ ọkọ rẹ, Ọgbẹni Aminullahi, lọ, to si bẹbẹ pe ki adajọ tu ibaṣepọ ọdun mọkanla to wa laarin awọn mejeeji ka.
Lara awọn ẹsun ti olupẹjọ ọhun ka si ọkọ rẹ lẹsẹ lasiko to n rojọ ni pe ki i tọju oun atawọn ọmọ meji tawọn bi. Naimọt ni lai ti i ku ọkunrin naa, oun nikan loun n da gbọ bukata lori awọn ọmọ. Obinrin to n ṣiṣẹ oogun oyinbo tita ọhun ni eyi to buru ju ninu ọrọ naa ni alubami ti olujẹjọ maa n lu oun nigbakuugba lori ọrọ ti ko to n kan. Fun idi eyi, ko si ifẹ mọ, ki adajọ tu awọn ka ki onikaluku maa lọ lọtọọtọ.
Abilekọ Naimọt ni loootọ lọkunrin naa san owo to to bii ẹgbẹrun marun-un Naira gẹgẹ bii owo-ori oun ki awọn too fẹra. Ṣugbọn oun ri i pe ko si ifẹ mọ laarin awọn mejeeji loun ṣe wa sile-ẹjọ lati jawee ikọsilẹ fun un.
O tẹsiwaju pe ọdun kọkanla ree ti awọn ti fẹ ara awọn niṣu-lọka, tawọn si bi ọmọ meji, ọkunrin kan, Abeeb, ati obinrin kan, Shukura.
Naimọt ni o ti le ni ọdun kan toun ti ko jade ninu ile ọkunrin abẹṣẹẹ-ku-bii-ojo toun pe ni ọkọ oun yii,, nigba to fẹẹ fi lilu yin oun lọrun, latigba naa ni ko si ti jẹ ki oun ri awọn ọmọ oun mejeeji mọ.
Bakan naa lo ni ki adajọ paṣẹ fun un pe o gbọdọ maa san owo ileewe, ounjẹ ati itọju awọn ọmọ rẹ loorekoore.
“Adajọ, ẹ dakun ẹ ba mi gba awọn ọmọ mi mejeeji ki wọn wa lakata mi, ki baba wọn si maa san owo ounjẹ ẹgbẹrun lọna aadọta Naira loṣooṣu, ko maa san owo ileewe wọn, ko si maa tọju wọn nigbakuugba to ba rẹ awọn ọmọ naa.”
Olujẹjọ Aminullahi, ko yọju si kootu lasiko ti igbẹjọ n lọ lọwọ.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ kootu ọhun, Ajibade Lawal Usman, ni ki Abilekọ Naimọt, lọọ wa ẹlẹrii meji wa lati waa jẹrii pe loootọ ni ọkọ rẹ maa n lu u. O sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun ta a wa yii.