Abẹ ọkọ oju omi lawọn eleyii sa pamọ si, wọn fẹẹ ba a deluu oyinbo

Jamiu Abayọmi

Lasiko ti ikọ NNS Beecroft ti ileeṣẹ ọmọ ologun ori omi lorileede wa Naijiria n ṣe patiroolu lori omi lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni wọn fọwọ ofin gba mu awọn ọmọkunrin marun-un kan,

Orukọ awọn afurasi ọdaran naa ni Effiong Okon, ẹni ọdun mẹrinlelogoji (44), Ayewuni Daniel, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27), Ajagboma Asiko, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29), Adebanjọ Ayewumi, ẹni ọdun mẹtalelogun (23), ati Christian Joseph, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25), nibi ti wọn pẹlẹngọ si labẹ ọkọ oju omi nla kan to fẹẹ rin irinajo lọ si orileede Spain.

Lasiko ti ọga ikọ to mu awọn ọmọkunrin maraarun ọhun, Kọlawọle Oguntuga n fa wọn le ajọ to n ri si iwọle ati ijade lọ silẹ okeere lolu ileeṣẹ wọn l’Apapa, niluu Eko, lọwọ l’Ọjọruu Wẹsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lo ti fidii ẹ mulẹ pe owuyẹ kan lo ta awọn lolobo nipa erongba awọn ọmọkunrin naa pe wọn fẹẹ ja pa lọ siluu oyinbo lawọn ba fi tọpasẹ wọn lọ, tọwọ fi ba wọn.

O ni, “Latari iṣẹ takuntakun ti ikọ pataki NNS ṣe ni wọn fi ri awọn maraarun ọhun mu nibi ti wọn kako si labẹ ọkọ oju omi to jẹ MSC Martha, to n lọ sorileede Spain.

“Ni nnkan bii aago mejila ku iṣẹju mẹwaa oru ọjọ Abamẹta, Satide, lọwọ ba wọn niluu Eko, lẹyin tawọn kan ta wa lolobo nipa igbeṣẹ wọn ọhun. Lẹyin tọwọ ba wọn tan ti a tu ara wọn la ba foonu, ohun eelo ara  ati owo to din diẹ lẹgbẹrun mẹjọ Naira”.

Ọga agba naa kadii ọrọ rẹ nile pe awọn afurasi maraarun ọhun ni wọn ti wa lakolo awọn agbofinro, tawọn yoo si ri i daju pe wọn gba ijiya to tọ labẹ ofin.

Leave a Reply