Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin ọlọkada kan, Nweke Peter, ti ha sọwọ ajọ sifu difẹnsi ipinlẹ Ondo, lori ẹsun pe o n fipa ba ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdogun kan lo pọ l’Akurẹ.
Alukoro ajọ naa nipinlẹ Ondo, Daniel Aidamenbor, ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, lọwọ tẹ ọkunrin naa nibi kan ti wọn n pe ni Willy Bright, Iyana Ẹlẹ́wà, Abuṣọrọ, lagbegbe Ijọka, niluu Akurẹ.
Nweke tan ọmọkunrin ta a forukọ bo laṣiiri ọhun lati ile-iwe rẹ lọ sile ara rẹ, nibi to ti fipa ṣe ‘kinni’ fun un titi di nnkan bii aago mẹfa irọlẹ, ko too yọnda ọmọ naa ko maa lọ.
O ni awọn araadugbo kan ti wọn ṣakiyesi pe irin ẹsẹ afurasi ọdaran ọhun ko mọ ni wọn ṣọ ọ titi ti wọn fi ri i mu, ti wọn si waa fa a le ajọ sifu difẹnsi lọwọ.
Aidamenbor ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keje yii, ni wọn ti kọkọ gbiyanju lati mu Nweke nigba ti wọn ka a mọ ibi to ti n ṣe ‘kinni’ fun ọmọ naa, ṣugbọọn o fọgbọn sa mọ wọn lọwọ ko too di pe ọwọ pada tẹ ẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
O ni ko si ani-ani pe ọkunrin ọlọkada naa ti ṣẹ si abala kọkanlelọgbọn ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo to n daabo bo ẹtọ awọn ọmọde tí ọdun 2007, ati abala kẹta ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo kan naa ti ọdun 2021, eyi to ta ko iwa ipa híhù.
Afurasi ọhun lo ni o gbọdọ foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii bá ti parí lori ẹsun ti wọn fi kan an.