Abilekọ kan dana sun awọn obi ẹ mọle ni Badagry

Monisọla Saka

Boya obinrin naa ni arun ọpọlọ ni o, boya eedi aye lo si di i, ko sẹni to ti i le sọ. Ṣugbọn ohun to daju ni pe obinrin ẹni ọdun mejilelaaadọta (52) kan, Aleremolen Izokpu, ti wo sunsun, to si sun awọn obi ẹ mejeeji, baba ẹni ọdun marundinlaaadọrun-un(85), ati iya rẹ to jẹ ẹni ọgọrin (80) ọdun, Ọgbẹni Michael Izokou ati Arabinrin Priscilla, mọle nipinlẹ Eko.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii, niṣẹlẹ naa waye lagbegbe City Gate Estate, Lusada, Okokomaiko, l’Opopona marosẹ Badagry, ipinlẹ Eko.

ALAROYE gbọ pe niṣe ni obinrin yii wọle tọ awọn obi ẹ lọ, awọn yẹn ko si ronu pe aidaa kankan wa lọkan rẹ to fee ṣe fun wọn, nigba to jẹ pe ko ṣẹṣẹ maa waa sọdọ wọn bẹẹ. Ohun to kọkọ ṣe ko too huwa ọdaju yii ni pe o lo oogun oorun fun baba ẹ, Ọgbẹni Michael Izokou ati Arabinrin Priscilla to jẹ mama ẹ. Lẹyin to ri i pe awọn mejeeji ti sun lọ fọnfọn, ni Aleremolen mọ-ọn-mọ sọ ina sinu ile naa, o si sa lọ patapata.

Loju-ẹsẹ lawọn to wa nitosi gbe wọn digbadigba lọ si ọsibitu, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe nibẹ naa lawọn dokita ti sọ fun wọn pe baba ti dagbere faye, ti wọn si gbe mama si abala awọn to nilo itọju ati amojuto gidi gan-an (ICU), nitori ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun niya naa wa.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundenyin, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe ni kete ti afurasi huwa ibi ẹ tan lo ti fẹsẹ fẹ ẹ. O tẹsiwaju pe ọkan ninu awọn aburo afurasi naa, Akugbe Izokou, lo lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa agbegbe ọhun leti, lẹyin ti ọkan ninu awọn aburo ẹ lobinrin pe e lori foonu lati sọ nnkan ti ẹgbọn wọn agba dan wo fun un.

Hundenyin ni, “Gẹgẹ bi alaye ti ọga ọlọpaa teṣan Okokomaiko ṣe fun wa ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila, ọdun yii. Wọn ni ẹni kan lo wọ teṣan wọn wa laago mẹta ọsan ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii, pe aburo oun obinrin torukọ ẹ n jẹ Osemudiame Izokpu, lo pe oun lori aago pe anti awọn, Aleremolen, ẹni ọdun mejilelaaadọta ti pa awọn obi awọn, lẹyin to lo oogun oorun to lagbara fawọn mejeeji, to si dana sun wọn mọle nigba to ri i pe oorun ti gbe wọn lọ.

“Bi ọkunrin yii ṣe n ṣalaye tan lawọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa ti lọọ bẹ ibudo iṣẹlẹ naa wo, lẹyin naa ni wọn ya si ile iwosan ti mama wọn to fara pa yannayanna ati oku baba to ti doloogbe wa, lẹyin ti wọn yẹ oku wo, ti wọn si ya aworan oloogbe ati mama to wa lori idubulẹ aisan ni wọn gbe oku baba agbalagba naa lọ si ile igbokuu-pamọsi ile iwosan nla ijọba, to wa ni Badagry “.

Hundenyin waa ṣeleri pe ọwọ awọn yoo ba afurasi naa pẹlu bi awọn ti ṣe bẹrẹ iṣẹ lori bi awọn ṣe maa mu un.

Leave a Reply