Jọke Amọri
Abilekọ Victoria Aguiyi-Ironsi to jẹ iyawo olori orileede Naijiria tẹlẹ, Ọgagun J.T.U Aguiyi-Ironsi, ti jade laye.
Laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn ni iya naa mi imi ikẹyin lẹni ọdun mẹtadinlọgọrun-un. Ti ki i baa ṣe iku to pa oju rẹ de, inu oṣu kọkanla, ọdun yii, ni iba pe ẹni ọdun mejidinlọgọrun-un loke eepẹ.
Ọkọ obinrin yii, Thomas Umunnakwe Aguiyi-Ironsi, lo fipa gbajọba lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 1966, to si di olori orileede Naijiria, ṣugbọn ti wọn pada pa oun naa lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 1966, lasiko iditẹgbajọba to waye lọdun naa.
Iyawo rẹ yii ko lọkọ mi-in m o latigba naa titi to fi jade laye lọjọ Aje ọsẹ yii.