Adewale Adeoye
Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ lọwọ, paroparo ni gbogbo inu ilu kan ti wọn n pe ni Mutunji, nijọba ibilẹ Maru, nipinlẹ Zamfara, da, afi bii ẹni pe oogun waa ko gbogbo awọn araalu naa lọ ni. Bẹẹ ko sohun meji to fa a ti ko fi seeyan kankan mọ laarin ilu naa ju pe wọn ko mọ igba tabi akoko tawọn agbebọn kan ti Ọgbẹni Damina ṣaaju wọn maa too tun pada waa kogun ja wọn gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe laṣaalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
ALAROYE gbọ pe ọjọ yii ni ogunlọgọ awọn agbebọn kan ti wọn jẹ ọmọ ẹyin Damina yii ya wọnu ilu ọhun lati waa gbowo ti wọn ni kawọn agbẹ inu ilu naa san fawọn ko too di pe wọn maa gba wọn laaye lati lọọ ko ire oko wọn lọdun yii.
Miliọnu lọna ọgọfa lawọn agbebọn ọhun n beere lọwọ awọn agbẹ ilu naa, bi wọn ṣe gun ọkada wọn wọnu ilu ọhun ni wọn ti yika gbogbo origun mẹrẹẹrin ilu yii, ti wọn ko si gba lati jẹ ki ẹnikẹni jade kuro ninu ilu naa rara. Ọkan lara awọn olugbe ilu ọhun to ṣe bii ẹni ṣaya gbangba ni wọn pa danu nibi to ti n ṣori-kunkun pẹlu wọn. Nigba tawọn araalu ọhun ko si r’owo tawọn agbebọn ọhun n beere fun ni wọn ba ko gbogbo wọn lẹru wọgbo.
Ọkan lara awọn olugbe ilu naa to gba lati ba awọn eeyan sọrọ, ṣugbọn to ni ki wọn forukọ bo oun laṣiiri fidi ẹ mulẹ pe aṣaalẹ ọjọ Furaidee yii lawọn agbebọn ọhun tun waa ko gbogbo awọn araalu naa lọ nitori ti wọn ko le sanwo ti wọn beere fun lọwọ wọn.
O ni, ‘‘Ni nnkan bii ọsẹ meloo kan sẹyin ni wọn wa sinu ilu wa ti wọn si sọ pe awọn ko ni i jẹ ki araalu kankan lọ sinu oko lati lọọ da oko tabi lati lọọ ko ire-oko rẹ wa sile, afi tawọn ba gba miliọnu lọna ọgọfa Naira (N120m) lọwọ awọn agbẹ ilu naa. Wọn ni kiluu Mutunji san miliọnu lọna aadọta, kiluu Fara, san miliọnu lọna ọgbọn Naira, kiluu Mahuta, san miliọnu lọna ogun Naira, kiluu Unguwan-Kawo, san miliọnu mẹwaa Naira, ti apapọ owo ti wọn n beere fun lọwọ awọn araalu ọhun si jẹ ọgọfa miliọnu.
‘‘Apa wa ko ka wọn rara mọ, aipẹ yii lawọn araalu wa ṣẹṣẹ gbe owo nla kan fun wọn, ki wọn le jẹ ka r’imu mi, ṣugbọn ohun ti wọn n beere fun lọwọ wa bayii ga ju ohun ta a le fun wọn lọ. Wọn wa saarin ilu wa ni aṣaalẹ ọjọ buruku naa, wọn paayan kan, bẹẹ ni wọn ji awọn araalu bii ọgọrun-un gbe sa lọ rau. Koda, wọn ji dukia awọn araalu kọọkan lọ lakooko ti wọn n ṣiṣe laabi ọhun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara, S.P Yazid Abubakar, to fidii iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ naa waye, ati pe awọn maa too bẹrẹ iṣẹ lori ọrọ ọhun, tawọn si maa fọwọ ofin mu gbogbo awọn to ba lọwọ ninu iwa laabi naa.