Gbenga Amos, Ogun
Ere lẹlẹẹlẹ ni baba awọn ọmọbinrin meji ti wọn jẹ tẹgbọn-taburo kan sa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Ajuwọn, nipinlẹ Ogun, to kegbajare fawọn agbofinro naa pe ki wọn gba oun lọwọ eemọ toun kan yii. O ni wolii ijọ Kerubu ati Serafu tawọn ọmọ oun, ọmọọdun mẹtala ati ẹgbọn rẹ, ọmọọdun mẹrindinlogun, n lọ, Joseph Ogundeji, ẹni ọgbọn ọdun, lo n ku awọn ọmọ naa mọlẹ pẹlu ibalopọ tipatipa, o si ti fun ọkan ninu wọn loyun.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, o ni ọjọ kọkanla, oṣu Kọkanla yii, lawọn agbofinro teṣan Ajuwọn lọọ fi pampẹ ofin gbe ojiṣẹ Ọlọrun afurasi ọdaran yii, lẹyin ti wọn ti gbọ ẹsun ti baba awọn ọmọ naa fi kan an.
Baba yii rojọ ni teṣan pe niṣe lawọn aladuugbo kan ta oun lolobo pe koun kiyesi ọmọbinrin oun, o jọ pe ọmọ naa ti fẹra ku, loun ba pe ọkan ninu awọn ọmọ ti wọn forukọ bo laṣiiri naa, lati mọ ọhun to ṣẹlẹ.
O ni niṣe loun kọ haa, nigba tọmọbinrin naa jẹwọ pe loootọ loun ti di abara meji, nigba toun si bi i pe ta lo fun un loyun, lo ba ni Wolii Ogundeji ni.
Awọn ọlọpaa ṣewadii lọwọ afurasi naa boya wọn purọ mọ ọn ni, ṣugbọn wolii yii ni ko sirọ nibẹ o, o loootọ ni, amọ oun kọ loun jẹbi, iṣẹ Eṣu ni.
Nigba ti iwadii n tẹsiwaju ni aṣiri tu pe jẹdejẹde ki i jẹ ọkan ṣiwọ ni wolii fawọn ọmọ baba yii ṣe, wọn ni bo ṣe n ba ẹgbọn laṣepọ naa lo n gun aburo bii kẹtẹkẹtẹ.
Awọn ọmọ naa ṣalaye pe ile ti wolii yii n gbe wa lẹgbẹẹ ṣọọṣi, wọn nigbakuugba tawọn ba ti waa ṣe iṣọ oru ni ṣọọṣi naa lo maa n sọ fawọn pe tiṣọọ oru ba ti pari laago mẹta oru, kawọn lọọ duro de oun nile rẹ ọhun, to ba si de ba awọn nibẹ, wọn lo maa n fun awọn ni kinni kan bayii la, tawọn ba ti la kinni ọran naa tan, niṣe lawọn maa n sun lọ fọnfọn, igba tawọn ba si taji lawọn yoo ri i pe jagunlabi ti kerewa labẹ wọn.
Wọn tun bi wọn leere idi ti wọn o fi fọrọ naa to obi wọn leti, wọn si fesi pe wolii yii ti kilọ gidi fawọn pe ẹda Ọlọrun kan o gbọdọ gbọ ohun to ṣẹlẹ lẹnu wọn o, tori iku ojiji lo maa ṣẹlẹ sawọn ti awọn ba fi sẹnu foro nipa ẹ, ẹru eyi ni ko jẹ kawọn fẹjọ rẹ sun.
Wọn tun bi wolii boya ootọ lawọn ọmọ yii sọ, ṣugbọn ko fesi mọ, niṣe lo kan n wolẹ ṣun-un, o ni ki wọn dariji oun.
Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki wọn taari Wolii Ogundeji si ẹka ti wọn ti n tọpinpin iwa ṣiṣe ọmọde niṣekuṣe ati ifiniṣẹru, o ni kawọn ọtẹlẹmuyẹ tubọ ṣewadii iṣẹlẹ yii daadaa, tori laipẹ ni afurasi naa yoo kawọ pọnyin rọjọ niwaju adajọ.