Monisọla Saka
Gbajugbaja akọrin ẹmi nni, Tọpẹ Alabi, tawọn eeyan n sọ oriṣiiriṣii ọrọ si nitori awọn ede to lo ninu orin to kọ nile-ijọsin kan laipẹ yii, ti sọrọ lori awuyewuye to n lọ lori orin naa.
Tọpẹ to fẹran lati maa lo awọn ijinlẹ ede Yoruba ninu awọn orin ẹ lo mẹnu ba abọru bọye ninu fidio orin tuntun to n ja ran-in lọwọ ọhun, lasiko to n kọrin lọwọ.
Apa kan ninu orin yii ni Tọpẹ ti sọ pe, “Abiye ni mi, orukọ mi niyẹn. Mo d’ẹbọ, mo ru, mo ye…”
Orin yii lo ti bi rogbodiyan lori ẹrọ ayelujara, bawọn ololufẹ Tọpẹ kan ko ṣe ri ohun to buru nibẹ, lawọn mi-in n bu u pe o ti yẹsẹ loju ọna Kristi to jẹ ipilẹ orin ajihinrere to n kọ. Bakan naa ni awọn ẹlẹgbẹ ẹ ti wọn jọ n kọrin ẹmi, atawọn aṣaaju Kirisitẹni mi-in n sọrọ buruku si i lori orin naa.
Bo tilẹ jẹ pe ni gbogbo igba tọrọ naa ṣi n gbona lọwọ, Tọpẹ Alabi ko sọ nnkan kan, ṣugbọn nigba to pada jade lati tan imọlẹ si ede to lo, tawọn eeyan kan ni ede awọn babalawo ni, Tọpẹ ni ijinlẹ ede Yoruba ni, ati pe awọn ọrọ bii ẹbọ jẹ yọ lawọn ibi kan ninu bibeli, awọn ede to jinlẹ, to si nitumọ yii si wa lara ami idamọ oun gan-an alara.
O ni, “A ri i ninu bibeli pe Dafidi rubọ igbagbọ si Ọlọrun. Abi ki lo de ti wọn o ṣe kọ irubọ ni ede Gẹẹsi tabi ede mi-in ninu Bibeli, ede Yoruba. Ede Yoruba ni, bẹẹ mi o si ro pe ede pataki kan wa fawọn oniṣẹṣe nikan. Gbogbo wa la jọ n sọ ede Yoruba yii.
Abrahamu rubọ ninu Bibeli, ṣe Ọlọrun ko gba a ni, abi ti Isaac ni ko gba?
Tawọn kan ba waa fẹẹ maa fi ede yii dara, ti wọn fẹẹ maa lo o bii ami idamọ wọn, ko sohun to buru nibẹ. Ti awa naa ba si gbero lati maa lo o, mi o ro pe o buru ju”.
Lati tubọ fidi ọrọ ẹ mulẹ, Tọpẹ Alabi gba inu iwe Roman, ori kejila, ẹsẹ kin-in-ni, lọ ninu bibeli, o ni, “Nitori naa, mo fi iyọnu Ọlọrun bẹ yin, ẹyin ara, ki ẹyin ki o fi ara yin fun Ọlọrun ni ẹbọ aaye mimọ, itẹwọgba, eyi ni iṣẹ isin yin ti o tọna’’.
Ọrọ pe o jẹ itẹwọgba yii ni ‘Abọru’, nigba ti ẹbọ aaye yẹn jẹ ‘Abọye”.
Oriṣiiriṣii ni nnkan tawọn eeyan sọ si ọrọ ti Tọpẹ wi yii lori ẹrọ ayelujara, nigba tawọn kan n ṣe kare fun un, pe ko jẹ dojuti awọn laelae, awọn mi-in ni bo ti wu ko jẹ ede Yoruba to, ki i ṣe eyi ti gbogbo eeyan le lo, pe to ba fẹẹ jarọ awọn, ko lọọ pariwo eriwo ya, aya gbo, aya tọ, ninu ṣọọṣi wo.
Niṣe lawọn mi-in ti ko ba wọn fi taratara da sọrọ naa n da wọn lẹkun lati ja mi lori ọrọ obinrin olorin ọhun, wọn ni ki wọn fi i lọrun silẹ.