Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori ti Fulani fi maaluu jẹ oko ẹ, ọkunrin agbẹ kan, Abraham Alamu, ti lu Fulani onimaaluu ọhun, Shuaib Adamu, pa.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2020 yii, niṣẹlẹ ọhun waye nigba ti Abraham gbẹmi odidi eeyan ẹlẹran ara bii tiẹ labule Ẹlẹga, niluu Ikoyi, nitosi Ogbomọṣọ, nijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Ọyọ, nitori ohun ọgbin inu oko rẹ ti awọn maaluu onitọhun jẹ.
Wọn ni oku Shuab ko dun un wo loju rara nitori bi ọdaju ọkunrin naa ṣe fi hámà fọ ọ lori pẹ́́tẹ́pẹ́tẹ́. Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ni kete ti ẹmi bọ lara Fulani onimaaluu naa loju ọkunrin agbẹ yii walẹ, to si na papa bora.
Ọsẹ kan lẹyin iṣẹlẹ yii, iyẹn, ọjọ Furaidee to kọja lọwọ awọn ajọ ẹṣọ alaabo ilu (sífú dì̀fẹǹsì), iyẹn Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC) pada tẹ ẹ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan, Agbẹnusọ fun ajọ ẹṣọ alaabo ilu nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Oluwọle Oluṣẹgun, sọ pe ni kete ti awọn pari iwadii awọn lori iṣẹlẹ yii lawọn ti fa afurasi ọdaran naa le awọn ọlọpaa lọwọ.
Lara awọn nnkan ija oloro to sọ pe wọn ka mọ Alamu lọwọ lasiko ti wọn mu un ni, hámà, ìyọ̀ṣó, sísọ́ọ̀sì, ayùn ati bẹẹ bẹẹ lọ.
SUGBON o ti di meelo ninu Fulani to n PA won ni Ile Yoruba ti won ti FI sekeseke si lowo bi eleyii,kii SE PE iwa ti omokunrin yii hu dara o,SUGBON kii won pin in re.
bi o tilẹ jẹ wipe iwa buruku ti o lodi sofin ni ipaniyan lootọ, o daju wipe ti o ba jẹ wipe ọwọ fulani ni o ju ti ọkunrin yi lọ ni ti o si ti gbẹmi rẹ nkọ? Ẹni ti o wa si inu oko eniyan ti o si ba ire oko na jẹ, ti o si tun laya diro ti oloko fi ba nibẹ, o daju wipe oun naa ti mura ija silẹ. Ọpọlọpọ igba ni iroyin ti fidi rẹ mulẹ wipe fulani pa awọn agbẹ sinu oko.
A fi ki Olorun saanu fun wa
Afi ki Olorun saanu fun wa
Ọrọ̀ Orílẹ̀ – èdè yìí ń fẹ́ àdúrà
Kodara ki a pa ómó énikeji wa sugbóñ iwa ti awóñ Fulani ñwu kodara.kosi ofin lorilede yi bi otin wu kokere mó.
ni ojo melo sehin ni emi naa de inu oko mi, okun ni mo busi nigba ti n ko lee da oko agbado mi mo, nitori won ko tile le bami see ku gaga igi agbado kan soso, won ti fi maalu je gbogbo re tan. Ki Olorun Olodumare gbawa ooo
Aare wa ni ka mu ise agbe lokunkundun sugbon ti awon Fulani awon eya re yi nko. Ti won n fi eran won je oko awon agbe nko, tabi ipaniyan lojojumo yi nko. Bo ba se Fulani lo pa Yoruba asegbe ni
To ba je Fulani lo paa Yoruba,ki ni ijoba Fe se si…..Fulani tin paa awon agbe tipe tipe ti ko si si nkan ti ijoba wa see si lati igba yi wa….won ko gbodo paa ooo otito ti Sonu lorile ede Nigeria.