Abubakar di Judasi, o fa ọga ẹ le awọn ajinigbe lọwọ niluu Ọwọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Baba ẹni ọdun mejilelaaadọrin kan, Suleman Abubakar, lọwọ ti tẹ fun  lilu ọga rẹ to gba a ṣiṣẹ ta ni gbanjo fawọn ajinigbe niluu Ọwọ.

Gẹgẹ bii alaye ti adari ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Adetunji Adelẹyẹ, ṣe fawọn oniroyin nigba to n ṣafihan baba agbalagba ọhun ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kejila, ọdun 2023 ta a wa yii.

Adelẹyẹ ni iṣẹ sikiọriti ni wọn gba Abubakar fun, to si ti wa lẹnu iṣẹ naa lati bii ọdun diẹ sẹyin.

O ni laipẹ yii lawọn ajinigbe kan waa ka ọga Abubakar mọle, ti wọn si ji i gbe lọ, ṣe ni wọn si kọ jalẹ lati tu ọkùnrin naa silẹ, ayafi igba ti wọn too gba owo nla, ọpọ igbo, siga, burẹdi atawọn nnkan mi-in lọwọ rẹ.

Ohun to pada tu aṣiri Abubakar to jẹ getimaanu baba olowo naa gẹgẹ bi a ṣe gbọ ni nọmba ẹrọ ibanisọrọ rẹ ti wọn ri nigba ti wọn n tọpa nọmba foonu tawọn ọdaran ọhun fi dunaadura owo ti wọn fẹẹ gba ki wọn too tu u silẹ.

Akọgun Adelẹyẹ ni lẹyin-o-rẹyin ni iwadii ti awọn ṣe nipa iṣẹlẹ naa pada fidi rẹ mulẹ pe Abubakar gan-an lo ta ọga rẹ fawọn to ji i gbe, nitori ọpọlọpọ ajọsọ ọrọ lo wa laarin wọn ki wọn too ji ọkunrin ti wọn f’orukọ bo laṣiiri ọhun gbe lọ.

Leave a Reply