Abubakar ji gbogbo ohun eelo to ba ninu yara otẹẹli to gbe ọmọge lọ n’Iyana-Iyẹsi

Faith Adebọla

Gẹgẹ bawọn alejo ti wọn nilo ibuwọsi ṣe maa n waa gba yara naa ni afurasi adigunjale ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Abubakar Mohammadu, gba yara kan ni otẹẹli Kẹkẹ, oun ati ọmọge ẹ kan ni wọn jọ wa, ṣugbọn ko ju wakati diẹ to wọbẹ lọwọ ba a nibi to ti n tu awọn nnkan eelo abanaṣiṣẹ ati dukia inu yara naa, o fẹẹ ji wọn ko sa lọ.

Ọga agba ajọ ẹṣọ alaabo So-Safe, nipinlẹ Ogun, Kọmandaati Sọji Ganzallo, to fiṣẹlẹ yii to Alaroye leti ninu atẹjade kan ti Oludari eto iroyin wọn, Moruf Yusuf, fi ṣọwọ laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keje, oṣu Ki-in-ni yii, o ni ni nnkan bii aago kan aajin oru ọjọ Ẹti, Furadee, lọwọ ba afurasi ọdaran naa ni agbegbe Iyana Iyẹsi, Ọta, nijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta, nipinlẹ Ogun.

Wọn ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ naa ni afurasi to loun n gbe adugbo Ọlọkọ, nijọba ibilẹ kan naa yii, wa sotẹẹli to wa n’Iyana Iyẹsi ọhun, oun ati ọmọbinrin kan ni wọn jọ wa, o loun fẹẹ gba yara kan mọju, wọn si fun un ni kọkọrọ lẹyin to sanwo tan, loun atobinrin ẹ ba ta koro si yara naa.

Wọn ni lẹyin wakati diẹ ni ọmọbinrin naa jade, o loun n lọ ile oun, aajin si ti jin nigba naa, bo ṣe de ẹnu geeti otẹẹli ọhun ni wọn da a pada pe ko le lọ, wọn o yọnda fun un, wọn ni ko pada sinu yara ẹ.

Awọn olotẹẹli yii tẹle e wọnu yara naa, tori wọn kọkọ ro pe nnkan aburu kan ti ṣẹlẹ ni, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn wọle, wọn ba alejo wọn, Abubakar, o ti tu awọn ẹrọ abanaṣiṣẹ bii faanu, waya kamẹra atanilolobo CCTV, awọn nnkan ẹṣọ, atawọn dukia mi-in silẹ, o si ti ko wọn jọ, ko ko wọn jade lo ku.

Awọn alaṣẹ otẹẹli ọhun ni wọn kan sawọn ẹṣọ So-Safe, oju-ẹsẹ si ni Idris Odukunle ,Alakooso So-Safe, ẹka ti Ilogbo, ati Igbakeji rẹ, Yusuf Samuel, pẹlu awọn ẹṣọ wọn kan ti lọ sibi iṣẹlẹ ọhun.

Wọn ba jagunlabi pẹlu awọn ẹru ẹlẹru to ji tu, wọn ni ko tiẹ fi mọ ni yara kan, odidi yara meji ni wọn lo ṣe baṣubaṣu, to tu awọn nnkan eelo wọn kalẹ, ni wọn ba fi pampẹ ofin mu un.

Ganzallo ni nibi ti wọn ti fẹẹ fi ankọọfun si afurasi yii lọwọ, o deyin mọ ika ọkan ninu awọn ẹṣọ So-Safe, o si ge e jẹ gidi,  ṣugbọn ago lo papa de adiẹ ẹ kẹyin, wọn mu un, wọn si ti fa oun atawọn ẹru ofin rẹ le awọn ọlọpaa lọwọ ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Onipaanu.

Wọn lọkunrin yii jẹwọ pe oun ko ṣẹṣẹ maa huwa laabi ọhun, o ti pẹ toun ti n fina jo awọn olotẹẹli labẹ aṣọ kaakiri, o si ti gbowọ sidii iwa alọ-kolohun-kigbe naa, kọwọ palaba ẹ to segi yii.

Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ yii, bi wọn ṣe wi.

Leave a Reply