Abubakar yii daju o, ọmọbinrin to fẹẹ fipa ba laṣepọ lo ṣa ladaa ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Fulani darandaran ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, Mohammed Abubakar, ti dero ọgba ẹwọn bayii, ile-ẹjọ lo paṣẹ bẹẹ, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o fẹẹ fipa ṣe ‘kinni’ fọmọbinrin kan, Mohammed Aishat, ati aburo rẹ. Nigba ti iyẹn ko gba fun un lo ba sa a ladaa lori yankanyankan.

Adajọ Gbadeyan Kamson  tile-ẹjọ Majisreeti to fikalẹ siluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lo juwe ọna ọgba ẹwọn fun afurasi ọdaran ọhun lasiko igbẹjọ rẹ to waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹfa yii.

Agbefọba, Ayẹni Gbenga, to ṣoju fun olupẹjọ sọ ni kootu naa pe Mohammed Aishat, lo mu ẹsun lọ si ileeṣẹ ọlọpaa ẹka tilu Lafiagi, nijọba ibilẹ Lafiagi, nipinlẹ Kwara, pe Fulani darandaran kan, Abubakar, da oun ati awọn aburo oun meji, Hassana ati Adishetu, lọna ninu igbo lasiko ti wọn lọọ ṣẹgi ti wọn yoo fi dana ounjẹ. O ni Fulani yii fẹẹ fi tipatikuuku ba oun laṣepọ, ṣugbọn nigba ti awọn ko gba fun un lo yọ ada, to si ṣa oun ladaa naa lori yankanyankan. Ọmọbinrin yii ni ọsibitu ijọba to wa niluu Lafiagi, lo gba ẹmi oun la lọwọ iku ojiji ti Abubakar fẹẹ fi pa oun lọjọ aipẹ.

O lawọn obi ọmọbinrin naa ni wọn mu ẹjọ Frank wa si teṣan awọn kawọn agbofinro too bẹrẹ iwadii, ti wọn si ri i pe afurasi naa huwa buruku ọhun.

O ni ẹṣẹ tọkunrin naa da ta ko isọri kẹrinladin ni ọtalerugba (246) ati ọkandinlọọọdunrun (299) iwe ofin ilẹ wa.

Adajọ Kamson ni o di asiko igbẹjọ to n bọ koun too tẹti si alaye rẹ. O ni ki wọn taari ẹ sọgba ẹwọn na, o si sun igbẹjọ si ọjọ Kẹwaa, oṣu Keje, ọdun 2023 yii.

Leave a Reply