Aburo Ayọdele Fayoṣe pariwo: Bi ohunkohun ba ṣe mi, ẹgbọn mi ati gomina Ekiti ni kẹ ẹ mu o  

‘’Gbogbo ẹyin ọmọ Naijiria, bi ohunkohun ba ṣe mi pẹnrẹn, ẹgbọn mi, Ayọdele Fayoṣe ati gomina ipinlẹ Ekiti, Abiọdun Oyebamiji, ni kẹ ẹ mu si i o’’. Wọnyi lọrọ to n jade lẹnu ọmọkunrin jayejaye to tun jẹ aburo gomina tẹlẹ nipinlẹ Ekiti, Isaac Fayoṣe, ẹni to fẹsun kan ẹgbọn rẹ ati gomina ipinlẹ Ekiti, pe wọn n lepa ẹmi oun.

Owe Yoruba kan lo sọ pe, ‘Bi ọmọọya meji ba wọle ti wọn ba ara wọn sọrọ, ti wọn roju koko jade, o han gbangba pe ootọ ọrọ ni wọn ba ara wọn sọ ni. Eyi lo ṣe rẹgi pẹlu ohun to n ṣẹlẹ laarin awọn ọmọ iya meji yii.

ALAROYE gbọ pe ohun to fa wahala yii ko ju awọn ikilọ ti ọmọkunrin naa maa n sọ lori ayelujara nipa iṣẹjọba gomina ipinlẹ Ekiti atawọn ohun to n lọ nibẹ, eyi ti ko dun mọ Ayọdele Fayoṣe ti i ṣe gomina tẹlẹ ati Ọlabanji to wa nibẹ bayii ninu.

Igba kan wa ti Isaac sọrọ nipa papakọ ofurufu ti Fayẹmi loun kọ sipinlẹ Ekiti lasiko to ku diẹ ki saa ijọba rẹ fẹnu bọpo. Papakọ ofurufu ọhun ko ṣiṣẹ, bẹẹ ni ko si ohunkohun teeyan le fi sọ pe iapọọtu lo wa nibẹ pẹlu owo rọngunrọgun ti wọn ni awọn na le e lori. Eyi ni aburo Fayoṣe ri to fi sọ pe Fayẹmi kowo awọn eeyan ipinlẹ Ekiti jẹ ni.

Laipẹ yii ni Isaac tun jade, to bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe n nawo ijọba nipinlẹ Ekiti, nibi to ti gba ijọba nimọran pe ki wọn ma fi owo ijọba ran awọn aṣofin Ekiti lọ si Canada. Bẹẹ lo tun ni ki wọn ṣe awọn ọna to bajẹ, ki wọn si yee na owo awọn eeyan ipinlẹ Ekiti ninakunaa, ki wọn yee fi owo ilu ra ile si Abuja, Eko, ati bẹẹ bẹẹ lọ. O ni awọn eeyan ibẹ lo yẹ ki wọn maa na an fun, ki i ṣe ki wọn maa ko o fun awọn eeyan tabi ki wọn maa fi ṣe awọn iṣẹ ti ko nitumọ, ti ko le ṣanfaani fun wọn.

 Bakan naa ni Isaac sọ pe awọn alaṣẹ ijọba pẹlu ifọwọsowọpọ ẹgbọn oun, Ayọdele Fayoṣe, ti n gbero lati ba eto ti awọn fẹẹ ṣe lati pin irẹsi bii igba ataabọ (250,000) atawọn nnkan mi-in fun awọn araalu ti ebi n pa. O waa pariwo pe ti ohunkohun ba ṣẹlẹ si oun, ẹgbọn oun, Ayọdele Fayoṣe ati Gomina ipinlẹ Ekiti, Abiọdun Oyebamji, ni ki wọn mu o. O fi kun un pe oun ko mọ ohun ti ẹgbọn oun fẹẹ ri gba ninu ohun to n ṣe yii.

 

Leave a Reply