Aburo mi ko jẹbi bo ṣe fọ ọlọpaa leti– Motunrayọ Kuti

Faith Adebọla

Ọtọọtọ lọrọ, ohun to kọju sẹnikan, ẹyin lo kọ sẹlomi-in bii ilu gangan, gẹgẹ bawọn agba ṣe n sọ, eyi lo difa fun bi ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe Fẹla Anikulapo Kuti, to jẹ gbajugbaja onkọrin Afrobeat laye ọjọun, Motunrayọ Kuti, ṣe jade lati gbeja aburo ẹ, Ṣeun Kuti, fun bi ọpọ eeyan ṣe n da a lẹbi iwa ọyaju ati arufin to hu laipẹ yii. Motunrayọ ni ko sohun to buru ninu nnkan ti ilumọ-ọn-ka olorin Afrobeat naa ṣe, o ni ko jẹbi bo ṣe fọ ọlọpaa leti, tori bi ko ba nidii, ẹṣẹ ki i deedee ṣẹ.

Ninu fọnran fidio kan ti obinrin naa ṣe, eyi to gbe sori ẹrọ ayelujara lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Karun-un yii, Motunrayọ ni oun ko le tẹle awọn eeyan ti wọn n sọ pe nnkan taburo oun ṣe pẹlu bo ṣe fibinu fọ ọlọpaa leti, to tun ta a laya leralera yẹn ko daa, tori wọn o si nibẹ lati mọ nnkan to ṣẹlẹ, ẹkun lo si ba ikun wa, o lohun ti ọlọpaa yẹn ti ṣe ṣaaju asiko yẹn, eyi to fa a taburo oun fi gbanajẹ bẹẹ.

Motunrayọ ni: “Emi o mọdi tawọn eeyan fi n binu, ti wọn koro oju si bi mo ṣe wa lẹyin aburo mi. Ẹyin n gbeja awọn ọlọpaa, ṣe ẹ waa fẹ k’emi naa to sẹyin yin lati ṣatilẹyin fawọn ọlọpaa lodi si aburo mi ni, abi bawo? Ki lẹ tiẹ n sọ gan-an? Emi o ro pe aburo mi jẹbi o, mi o si ri nnkan ti ko daa ninu ohun to ṣe. Aburo mi o jẹbi rara. Ko sẹni to kan le wo ṣun-un ṣun-un, ti yoo kan dide, ti yoo si maa fun ọlọpaa ni ifọti lai nidii. O ni lati jẹ pe aigbọra-ẹni-ye kan tabi aawọ kan ti wa nibẹ ni.”

Obinrin naa tun sọ pe: “Ẹ jọọ o, ẹ jọọ, mo bẹ yin ni o. Eleyii o ki i ṣajeji wa, o ti mọ wa lara, gbogbo igba lawọn agbofinro n ri si wa, iyẹn o si jẹ tuntun. Tori ẹ, ẹru o ba wa, aya o si fo wa, a maa yanju ẹ naa ni. Mi o lọrọ pupọ lati sọ, a ti n bojuto ọrọ ọhun, a si jọ maa yanju ẹ ni,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to lọ yii, lawọn ọlọpaa Eko wọ Ṣeun rele-ẹjọ lori ẹsun pe o ṣakọlu si ọlọpaa kan nirona, lori afara Third Mainland bridge, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un yii.

Eyi lo mu ki ọga ọlọpaa patapata paṣẹ ki wọn lọọ fi pampẹ ofin gbe e, ki wọn si ba a ṣẹjọ lori iwa ọyaju naa. Ọpọ araalu ni wọn dẹbi fun Ṣeun lori ẹrọ ayelujara latari iṣẹlẹ naa. Ile-ẹjọ Majisreeti kan ni Yaba ti wọn wọ afurasi naa lọ ti paṣẹ ki wọn fi i sahaamọ fun ọjọ meji, ki wọn si gba beeli rẹ, amọ nigba tawọn ọlọpaa tun rawọ ẹbẹ pe awọn o ti i pari iwadii awọn, tori awọn ti lọọ gbọn ile Ṣeun yẹbẹyẹbẹ, awọn si ri awọn aṣiri kan nibẹ to le ran igbẹjọ naa lọwọ, ile-ẹjọ tun pero da, wọn fi ọjọ mẹrin-in kun asiko ti Ṣeun yoo fi wa lahaamọ wọn ọhun.

Leave a Reply