Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Eeyan mẹta lo gbẹmi mi ninu kanga kan lagbegbe Alaro Onigbin, niluu Owode-Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
Awọn mẹtẹẹta naa, Adebayọ Oluwaṣina, ti wọn pe ni pasitọ jẹ ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta, Lateef Adediran jẹ ẹni ọdun mejilelogun ati Waliu Adediran toun jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, ni wọn pade iku ojiji ninu kanga to wa niwaju ile ti pasitọ naa n kọ lọwọ.
Gẹgẹ bi ẹnikan laduugbo naa ti ko fẹ ka darukọ oun ṣe ṣalaye, iṣẹ birikila ni Waliu ati aburo rẹ, Lateef, n ṣe, iṣẹ aje yii naa lo gbe wọn de Owode-Ẹdẹ, lọjọ iṣẹlẹ yii.
O ni ifami ti wọn fi n fa kanga yii lo ja sinu kanga, Lateef to n fami lọwọ si bọ sinu rẹ lati yọ ọ jade, ṣugbọn ko le jade mọ.
Idi niyi ti Waliu to jẹ ẹgbọn rẹ naa fi ko sinu kanga lati yọ Lateef, ṣugbọn ṣe loun naa dakẹ sibẹ, eyi lo fa a ti pasitọ funra rẹ fi pinnu lati wọnu kanga ọhun, ṣugbọn oku awọn mẹtẹẹta ni wọn pada gbe jade.
Agbẹnusọ fun ajọ panapana nipinlẹ Ọṣun, Ibrahim Adekunle, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni gaasi olooru kan (ammonia gas) to wa ninu kanga ọhun lo ṣeku pa wọn.
Adekunle ṣalaye pe loju-ẹsẹ ti wọn pe ajọ panapana lawọn debẹ, ti awọn pẹlu awọn ọlọpaa ‘A’ Division, niluu Ẹdẹ, si jọ ko awọn mẹtẹẹta jade ninu kanga naa.
O ni nigba tawọn ko wọn de ọsibitu kan ni awọn dokita fidi rẹ mulẹ pe awọn mẹtẹẹta ti jade laye, loju-ẹsẹ ni wọn si ko oku awọn mẹtẹẹta fawọn mọlẹbi wọn.